Inter-Party Advisory Council (IPAC), Ẹgbẹ́ Ìgbìmọ̀ Àgbáríjo Àwọn Ẹgbẹ́ Óṣèlú ní Ìpínlẹ̀ Ogun, ti ké sí gbogbo àwọn ẹgbẹ́ àti aṣáájú òṣèlú láti ṣiṣẹ́ fún ìṣọ̀kan, ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú bí ìmúrasílẹ̀ ìdìbò gbogbogbò ọdún 2027 ṣe ń bi lọ́nà.
Ìpè náà wáyé níbi ìpàdé pàtàkì kan tí IPAC Ogun State ṣe lábẹ́ alága, Ọjọgbọn Sanyaolu Abayomi. Eyi ti alukoro wọn Ọnarebu Ṣeyifunmi Adeyẹmi gbe jade
Ìpàdé náà dá lórí bí a ṣe lè túbọ̀ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàárín àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú, pẹ̀lú ìbáṣepọ̀ tó ní lálàáfíà, kí ètò óṣèlú tó ba ófin mu àti tó ní ojúṣe rere fún ìpínlẹ̀ Ogun ni ọdún 2027.
Ẹ̀gbẹ́ IPAC Ogun State tún lo ànfààní ìpàdé ọ̀ún láti kí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú márùn-ún tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ darapọ̀ mọ́ IPAC káàbọ̀ sí inú ìdīlé IPAC.
IPAC sọ pé ìdarapọ̀ àwọn ẹgbẹ́ tuntun wọ̀nyí yíò túbọ̀ ń mú kí ìgbìmọ̀ náà lágbára gẹ́gẹ́ bí àgọ́ kan tí gbogbo àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọ́n forúkọ sílẹ̀ lè ti kópa, sọ̀rọ̀ àti gbọ́ ohùn wọn, nígbà tí ire, àlàáfíà àti ìdàgbàsókè gbogbo ènìyàn ìpínlẹ̀ Ogun yóò jẹ́ ohun àkọ́kọ́.
IPAC ìpínlẹ̀ Ógún sàlàyé pé ìgbìmò àwọn dúró ṣinṣin lórí ìgbàgbọ́ nínú ìjọba tiwa-n-tiwa tó ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ètó ìṣèlú tí ó fi àwọn ènìyàn lọkàn balẹ̀, ìbáṣepọ̀ àlàáfíà àti àbójútó ogún ìjọba tiwa-n-tiwa ni ìpínlẹ̀ Ogun.
Ìgbìmọ̀ àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú náà tún sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ pínpín agbára àti aṣojú óṣèlú ní ẹlẹ́kūnjẹkūn ní ọdún 2027, ó sì kéde pé káàkiri àwọn agbègbè Sẹ́nẹ́tọ̀ mẹ́tẹ̀ta tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Ogun gbọ́dọ̀ ní àǹfààní dọ́gba láti mú àwọn tó fẹ́ díje fún àwọn ipò ìjọba jáde.
Gẹ́gẹ́ bí IPAC ṣe sọ, kò yẹ kí a ka agbègbè Sẹ́nẹ́tọ̀ kankan sí ẹni tó ní ẹ̀tọ́ títí láé sí ipò òṣèlú kan, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ kí a máa yọ agbègbè kankan kúrò nínú àǹfààní láti gba ipò ìjọba.
IPAC tẹnumọ́ pé ọgbọ́n àti ìmọ̀, ìwà rere, agbára iṣẹ́, ìgbẹ́kẹ̀lé, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìbáṣepọ̀ gidi pẹ̀lú ìpínlẹ̀ Ogun ló yẹ kí ó wà lára àwọn ohun pàtàkì tí àwọn ènìyàn yóò fi ṣe ìpinnu ẹni tí wọ́n fẹ́ gbẹ́kẹ̀ lé.
Gẹ́gẹ́ bí àlàkalẹ̀ eto ìṣèjọba tiwantiwa olúkúlùkù ènìyàn àti ẹgbẹ́ òṣèlú lo ni ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin láti du ipò òṣèlú tí o bá ní ìfé sí.
Àjọ, IPAC kìlọ̀ pé kò yẹ kí àǹfààní àti ọjọ́ ọ̀la gbogbo ènìyàn ìpínlẹ̀ Ogun di ohun tí ẹnìkan, ẹgbẹ́ òṣèlú kan tàbí àwọn alágbára kan le máa lò fún àǹfààní ara wọn nìkan.
Ìgbìmọ̀ náà ṣàkótán ìpò rẹ̀ pé:
Gbogbo agbègbè sẹnitórià kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ sí àǹfààní tó dọ́gba bákannáà àti pé gbogbo ọmọ Ogun tó jẹ́ ẹni tó ní ìgbẹ́kẹ̀lé, tó ní ìwà rere, agbára àti ìmọ̀ tó yẹ gbọ́dọ̀ ní àǹfààní láti fi ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ètò ìsèjọba.
Bí ìmúrasílẹ̀ ètò ìdìbò ọdún 2027 ṣe ń lágbára síi ni IPAC Ogun State yóò máa tẹ̀síwájú nínú gbígbé ìjíròrò òṣèlú, ọ̀wọ̀ ara ẹni àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó dá lórí àǹfààní gbogbo ènìyàn lárugẹ láàárín àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú àti gbogbo àwọn tó kópa nínú ètò ìṣèlú ní ìpínlè Ògūn.
No comments:
Post a Comment