Oludije fẹgbẹ oṣelu NDC, fun ipo aṣofin agba fun ẹkun agbegbe aarin gbungbun, Ogun Central, Ọnarebu George Taylor, ti gba gbogbo awọn ọmọ orileede yii lamọran lati maa tubọ fi adura ran orileede yii lọwọ, nitori ireti ṣi wa ayipada rere si n bọ wa.
O sọrọ yii ninu atẹjade to fi sita fun ti ayẹyẹ ọdun kẹrindinlaadọrin ti orileede yii gba ominira, eyi to n lọ lọwọ.
O kọkọ ki awọn ọmọ orileede yii ku oriire ayẹyẹ ajọdun to n lọ lọwọ naa pẹlu awọn ilakọja ti wọn ti foju winna.
George tun fikun ọrọ ẹ pe oun nigbagbọ pe atunbọtan orileede yii yoo dara tawọn ti wọn foju winna yoo pada ja si ayọ.
O ṣalaye ṣiwaju pe bi ibo ṣe sunmọ ki awọn ọmọ Naijiria lo anfaani ọhun lati fi dibo fun Peter Obi, oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu NDC, ninu ibo to n bọ.
O ni lakooko ta a wa yii ẹni ti Ọlọrun fẹẹ lo lati gba awọn ọmọ Naijira kuro lọwọ inira ti ẹgbẹ oṣelu APC ko wa si lati bi ọdun meloo sẹyin ni Peter Obi.
George tun ṣapejuwe oludije wọn gẹgẹ bi ẹni to ti ni iriri bi wọn ṣe le ṣakoso lọna ti ọpọ awọn araalu yoo jẹ anfaani to pọ.
O ni kawọn ọmọ orileede yii ma sọ ireti nitori bi Peter Obi ba wọle yoo mu ayipada rere wa.
Bakan naa lo tun jẹ kawọn eeyan to fẹẹ ṣoju fun nile igbimọ aṣofin agba iyẹn Ogun Central pe oun ko ni jawọn nitan an mọ bi wọn ba le fi ibo gbe oun wọle labẹ NDC.
Bakan lo tun tẹnumọ fawọn araalu pe ki wọn dibo fun ẹri ọkan wọn ninu ibo to n bọ ọhun, nitori oun mọ pe bi ẹgbẹ oṣelu APC, ti ṣe su wọn lati oke wa bẹẹ naa lo tun su wọn nipinlẹ Ogun, nitori iṣejọba wọn ti su araalu.
O wa ṣeleri pe bi ẹgbẹ NDC ba fi wọle irọrun ni yoo jẹ fawọn araalu, ni pari, o tun ki awọn ọmọ orileede yii ku ajọyọ nla ti ominira.
No comments:
Post a Comment