Bo tilẹ jẹ pe ninu idajọ ọhun awọn adajọ ọhun ko darukọ pe oloṣelu tabi oludije kan bayii lawọn n ba wi, ṣugbọn awọn oloṣelu ti wọn wa nipinlẹ Ogun sọ pe bi wọn ba ṣagbekalẹ idajọ ọhun ati bi Iyabọ Ọbasanjọ ṣe jade dupo aṣofin agba labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, fun ẹkun Ogun Central, ko koju oṣuwọn.
Wọn bi wọn ba wo abala ofin eto idibo tawọn adajọ ile ẹjọ giga ọhun gbe idajọ le lori iyẹn abala 77. Ẹgbẹ oṣelu ko gbọdọ forukọ ẹnikẹni silẹ lẹyin akoko yii. Ẹgbẹ oṣelu to ba kuna lati forukọ silẹ lawọn akoko ọhun yoo padanu aye tabi ipo naa.
Wọn ni Iyabọ Ọbasanjọ ko jẹ oludije iyẹn jẹ ara aṣiṣe ti ajọ eleto idibo ti kọkọ ṣe latilẹ, ti wọn fi gbe orukọ ẹ jade.
Bẹẹ ni wọn sọ pe gbogbo ilana ati ibamu ofin ti wọn la silẹ fun oludije ẹgbẹ oṣelu lo kuna lati mu ṣẹ.
Wọn ni ki ni nnkan to n fẹẹ to ṣa fẹẹ fi tipa dupo, wọn ni oun yii kan naa lo fẹẹ ṣe gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, oun yii naa lo tun gba PDP, lọ to fẹẹ ṣe aṣofin.
Wọn ni orukọ ẹ ko si ninu ọmọ ẹgbẹ PDP, ti wọn fi sọwọ si ajọ eleto idibo laarin ọjọ mọkanlelogun ki wọn to ṣe pamari gẹgẹ bi ilana ofin abala 77 ṣe wi.
Bẹẹ ni wọn ran ajọ eleto idibo leti pe ofin kan wa iyẹn abala 84, iyẹn ti wọn ba fẹẹ fi tipa forukọ ẹ silẹ gẹgẹ bi oludije.
No comments:
Post a Comment