Arabambi ko tọ lẹni to le ṣoju ẹgbẹ apapọ oloṣelu nipinlẹ Ogun nitori ko ni orukọ rere nilẹ-IPAC - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 17 September 2026

Arabambi ko tọ lẹni to le ṣoju ẹgbẹ apapọ oloṣelu nipinlẹ Ogun nitori ko ni orukọ rere nilẹ-IPAC

Alaga fẹgbẹ apapọ oloṣelu nipinlẹ Ogun iyẹn IPAC, Kọmureedi Abayọmi Sanyaolu, lorukọ ẹgbẹ naa ti tako bi ẹgbẹ oṣelu APC, ṣe darukọ  Abayọmi Arabambi gẹgẹ bi alaga igbimọ laarin awọn ẹgbẹ oṣelu fun ti ipolongo ibo.

Ninu atẹjade kan to tẹ wa lọwọ, ni ẹgbẹ IPAC  ti yari kanlẹ pe bi APC, ṣe darukọ oloṣelu ọhun ku diẹ kaato bẹẹ ni ko si ni itẹsiwaju wọn.

Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, wọn ni loootọ ni APC  le yan ẹni to ba wu wọn fun igbimọ lọkan ara wọn amọ ki i ṣe iru Arabambi, nitori wọn ni ko ni akọọlẹ rere ati iwa-otitọ.

Bẹẹ ni wọn ni ko tun ni ipo to tọ lati ṣe aṣoju tabi ba awọn ẹgbẹ oloselu sọrọ lorukọ IPA ipinlẹ Ogun.

Sanyaolu tun sọ pe orukọ Arabambi ko tun si lara oloye ẹgbẹ oṣelu kan yala ni apapọ tabi tipinlẹ ti ajọ eleto idibo INEC  gbe jade.

IPAC  ni ẹnikẹni ti wọn ko gba laaye ninu ẹgbẹ oṣelu kan ko yẹ ki wọn maa fun iru ẹni bẹẹ laaye.

Wọn wa gba APC lamọran lati maa ṣewadii finnifini lori ẹnikẹni ti wọn ba fun niṣẹ ṣe ko to di pe wọn gbe orukọ ẹ jade faraye.

No comments:

Post a Comment

Pages