Agba oniṣehun ọhun ti yoo tun joje Aarẹ Aṣipa ti Odo ọna nla, Idi Ayunrẹ, niluu Ibadan, lọjọ Ẹti, Furaide ọsẹ yii, sọrọ naa lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ.
O sọ pe, " Akọkọ naa iṣẹ iṣegun yii ajogunba ni, baba mi jogunga ba a ni, nitori baba mi daa silẹ ni 1981, awọn naa jogunba lọdọ baba ti wọn naa.
"Ọgbọn igbalode ti wọn fi daa silẹ nigba naa ko to di pe emi naa jogunba ti mo waa gbe iṣẹ naa lọ siwaju.
"Ti eeyan ba ṣi jogunba nnkan, o maa n ṣe ju bẹẹ lọ ni ọna ti yoo fi ba igbalode mu, ti yoo fi maa tẹsiwaju.
"A wa imọ ati ẹkọ lati le fi sun siwaju, nitori bi a ba ni nnkan taa jogunga, la maa jokoo ti, imọ yẹn ko nii lọ siwaju.
"Ẹni to ba si jokoo tẹtẹrẹ ti ko wa imọ kun imọ, ti ko wa iṣẹ kun iṣẹ, ko ni le sun siwaju fun imọ ni, ki imuṣẹ Olodumare nipa ayanmọ, le tẹsiwaju, eeyan gbọdọ ni lati ṣewadii fun imọ.
O fikun ọrọ ẹ pe ọmọ bibi ipinlẹ Ondo loun ṣugbọn Ibadan ni wọn bi oun si tileeṣẹ oun naa wa nibẹ pẹlu.
O ni awọn maa n fi tewe tegbo wọn gba ọmọ eeyan la bẹẹ lawọn si tun fi n wo wọn san.
Bakan naa lo sọ pe, "Akọsilẹ wa pe ori ni n da ni, a kii da ori, ooṣa ni pa nii da, a ki i pa ooṣa da, ipin la fi n bi arẹmọ.
"Ipin ti ooṣa temi pin fun mi ni pe ka maa ṣe ọdun iṣẹṣe temi ni ọjọ kẹfa, oṣu kọkanla, ni gbogbo ọdun.
"Bijọba ṣe fa Ogunjọ oṣu kẹjọ kalẹ, ki i ṣe nnkan to buru, wọn fa kalẹ fun agbajọpọ lati maa ṣe iṣẹṣe, bi ẹ ba wo awọn onigbagbọ atawọn musulumi, nijọba naa fa ọjọ kan kalẹ fun wọn, eleyii dara pupọ.
"Lẹyin ọdun iṣẹṣe gbogboogbo yii lawa maa n ṣe tiwa iyẹn ọdun olokun.
Nigba to n sọ nipa Iṣẹṣe, Aarẹ Babalọla sọ pe, " Bi a ba n sọrọ nipa iṣẹṣe mo ni lati pẹtu si ero ọkan ati irori wa, awọn kan sọ pe ẹsin ni ṣugbọn lọdọ temi iṣẹṣe ki i ṣe ẹsin.
"Idi ni pe iṣẹẹṣe ki i ṣe nnkan ta a n sin, ti a wa maa sọ pe ọjọ bayii o nnkan bayii ni a maa ṣe, baba, iya, iṣẹ ẹni, iṣẹṣe ni gbogbo wọn ati iwa pẹlu, bi a bo woo daadaa, awa ọmọ Yoruba, a ki i ṣe ẹlẹsin, iwa, ọrọ, ede wa ni ẹsin wa.
"Bakan naa lo tun jẹ pe imura wa, iseeṣi ati ile taa ti wa naa tun jẹ ẹsin pẹlu.Ki i ṣe nnkan tawọn eeyan kọ sinu iwe tabi fi tipa mu pe a gbọdọ maa ṣe.
"Ni afikun iṣẹṣe tun nii ṣe pẹlu awọn oriirun wa,iranti awọn ooṣa wa, mimu akọsilẹ wọn lo, ṣiṣe ọdun ati ayẹsi wọn.
"Baba ati iya wa to ti lọ taa n pe wọn ni eegun ọrun.A ni lati maa ṣe iranti wọn, awọn ooṣa atawọn alaalẹ, ki a maa gbe wọn larugẹ.
"Nitori onikaluku ni Ọlọrun fun ni oore ọfẹ lati ṣe ẹsin to ba wuu, eyi wu mi, ko wu ẹ.Gẹgẹ bi erongba ati iṣẹ ti mo gbe dani, a ki i fi ipa mu eeyan, ko si ninu iṣẹṣe.
"Ko si ipanle ẹsin lọdọ temi, ṣugbọn a maa tọ wọn sọna, o wa ku si i lọwọ lati yan ẹsin to baa wu.
Agba oniṣegun naa tun sọrọ lori oye to fẹẹ jẹ lọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ yii, o sọ pe, " Mo dupẹ lọwọ Olodumre pe o ka mi yẹ lati jẹ ọkan lara awọn oloye niluu Ibadan , mo dupẹ lọwọ Olubadan tiluu Ibadan, Ọba Abdul Rasheed Adewọlu Ladọja, bẹẹ ni mo tun dupẹ lọwọ ọba ti Odo- ọna nla, Baalẹ idi Ayunrẹ, Emmanuel Bello, lori bi wọn ṣe kamiyẹ mọ awọn ti yoo maa ba wọn ṣelu ni Odo nla.
"Oye Aarẹ Aṣipa nilukilu jẹ pataki, gboogi ti ko ṣe fọwọ rọ sẹyin nilẹ Yoruba. Ohun to bi oye yii ko jinna, gẹgẹ bi mo ṣe sọ siwaju iwa, iṣẹ ẹni iṣẹṣe ni ati ọmọluabi,awọn nnkan to bii niyẹn.
Bẹẹ lo ni ara adura toun maa n gba ni pe ki ọmọ rere jogun oun bẹẹ adura yii ni baba oun gba toun naa fi jogun iṣẹ rere ti o ṣe.
O ni, "Ohun ni mo n gba ki ọmọ rere jogun mi, ki oun naa le tẹsiwaju nidii iṣẹ yii. Nitori Yoruba bọ, wọn sọ pe bina ba ku, a fi eeru boju, bi ọgẹdẹ ba ku, a fi ọmọ rẹ rọpo.
"Ooṣa taa ba fi le ọmọ lọwọ, irufẹ bẹẹ maa n parun ni, iṣẹ wa ko ni parun o, iṣegun, babalawo, iṣẹ to muu yangan to to nii gba ni.
Aarẹ ni lati dẹkun iwa palapala laarin awọn oniṣẹṣe, oun fẹẹ ki gbogbo wọn ṣe ara wa ni ọkan, wọn gbọdọ kọkọ ṣara wọn jọ, ki araata to le fẹran wọn.
O ni, "Ẹlẹẹkeji, ki a jẹ kijọba ṣe tẹwọgba wa, bi wọn ṣe ṣe ṣi iṣeeṣe yii, ti wọn ba rii pe a lẹsẹ nilẹ, wọn ko ni tabuku, ẹnikọọkan wa.
"Ẹlẹẹkẹta ni pe ki a jẹ ki wọn mọ pe ko sẹni to le fi ipanle mu ẹnikẹni lati ṣe ẹsin kan. Yoruba ni a kọkọ jẹ, ka to sọ pe ẹsin, eeyan ni a kọkọ jẹ ko to di pe a jẹ ẹya.
"Ifẹ lo yẹ ko gbilẹ lọkan onikaluku, ko nii ṣe pẹlu ẹsin to n ṣe,ki a fẹran ara wa, to ba ti wa ko ni sija tabi ẹlẹsin mẹsin.
"Awọn ti oye ko ye ni wọn maa n sọ pe awọn ko fẹẹ ri oniṣẹṣe, nitori pe gbogbo ọna to lọ sọdọ Olodumre lo pọ.
"Ẹni to ba sọ pe nitori ẹsin oun ko fẹẹ ri ọmọnikeji oun, onitọhun n fẹ ayẹwo, ko si ye ko maa gbe lawujọ eeyan.
"Ati pe iṣẹẹṣe ti wa kawọn ẹsin atọhunrinwa to de, ẹsin tawọn babanla wọn sin, ko to di pe wọn ko ajoji si wọn lori.
"Wọn kọkọ maa n mu ọpọlọ wọn wọle, ko to di pe wọn mu awọn naa lẹru. Awọn ẹsin ẹru amunisin lo maa n fa a ki eeyan maa sọ pe oun korira ọmọnikeji oun nitori ẹsin to n ṣe.
No comments:
Post a Comment