Igbimọ lọbalọba Agbado tako oye iyalode jẹnẹra ti wọn fẹẹ fi Ayọka Agboke jẹ nijọba ibilẹ Ifọ. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 14 August 2026

Igbimọ lọbalọba Agbado tako oye iyalode jẹnẹra ti wọn fẹẹ fi Ayọka Agboke jẹ nijọba ibilẹ Ifọ.

Laarin ọsẹ yii ni igbimọ lọbalọba tijọba ibilẹ Ifọ kede Iyalode tilu Agbado, Oloye Ayọka Agboke gẹgẹ bi Iyalode gbogboogbo nijọba ibilẹ ọhun.

Ninu lẹta kan tawọn igbimọ lọbalọba tijọba Ifọ lẹta fi ranṣẹ si obinrin naa, nibi ti wọn ti yan an gẹgẹ bi iyalode gbogboogbo, eyi ti Ọba Sulaiman Adekunle Bamgbade Ayọdele, Ọlọfin tiluu Iṣhẹri fọwọ si lorukọ igbimọ lọbalọba ọhun.

Nibẹ ni wọn ti kan sara sii sawọn akitiyan ẹ nigba to ṣakoso gẹgẹ iyalode Agbado gẹgẹ bi akọni obinrin to si ti mu idagbasoke ba ilu naa, tawọn si nigbagbọ pe yoo tẹsiwaju lakooko to di Iyalode jẹnera bayii.

Ko si pẹ ti lẹta tun fi jade lati ọdọ Ọnarebu Idris Ọlalekan Kusimọ, alaga ijọba ibilẹ Ifọ, nibi to ti fọwọ si fifi Ayọkaẹ̀ Agboke jẹ Iyalode jẹnẹra.

Ninu lẹta loun naa ti sọ pe oun nigbagbọ pe bawọn ọba alaye ọhun ṣe yan Iyalode jẹnẹra yoo tubọ mu isọkan, ifẹ ati alaafia ba gbogbo igbimọ lọbalọba ati ijọba ibilẹ lapapọ.

Loju ẹṣẹ ni ẹgbẹ kan to jẹ ti ọdọ niluu Agbado taa mọ si Agbado Youth Forum nile ati loke okun ti ranṣẹ oriire si Iyalode ọhun fun agbega nla ti wọn mu ba a.

Ṣugbọn ni bayii, igbimọ lọbalọba tilu Agbado ti yari kanlẹ pe awọn ko fọwọ si igbesẹ yiyan Oloye Ayọka Agboke iyẹn gẹgẹ bi iyalode jẹnẹra.

Ninu iwe atẹjade ti wọn fi sita ni wọn ti sọ pe bigba ti wọn fẹẹ fọrọ naa da wahala silẹ niluu ni ati pe o tako ofin ipinlẹ Ogun ọdun 2021.

Wọn ni ko si labẹ ofin ipinlẹ Ogun to faye gba idasilẹ oye Iyalode jẹnẹra, wọn ni ko saaye fun alaga ijọba ibilẹ lati yan iru oye bẹẹ.

Igbimọ lọbalọba ilu Agbado tun sọ pe awọn igbimọ lọbalọba ti wọn ṣe tẹwọgba ẹ nipinlẹ Ogun ni Ẹgba, Ijẹbu ati Yewa, ninu eyi ti ijọba ibilẹ Ifọ wa labẹ wọn. Ko si
 eyi to wa labẹ wọn ti wọn fun laṣẹ lati iru oye bẹẹ labẹ wọn.
 Atẹjade ọhun tun tẹsiwaju pe, " Adajọ S M Owodunni tile ẹjọ giga kan ti agbegbe Ipokia ti gbe idajọ kan kalẹ lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu karun-un ọdun 2017, ti iwe ipẹjọ ẹ jẹ HCT/199/2012, pe Oloye Akinrinade ki i ṣe ọba tabi baalẹ ni Agbado, bẹẹ ni ko laṣẹ labẹ ofin lati yan oloye kankan niluu naa. Eyi to tumọ si pe gbogbo oloye to yan ni wọn fagile.

"Ni afikun ijọba ibilẹ Ifọ, ko gbọdọ moju kuro ninu lẹta ti ijọba ipinlẹ Ogun gbe jade labẹ ileeṣe yiyan oloye, eyi ti wọn ti ran wọn leti pe wọn ko gbọdọ fun oloye kankan ti wọn ko ba tii ṣe tẹwọgba ni iwe ẹri.

"Ati pe ko sigba tabi akoko kan nibi ipade lọbalọba ijọba ibilẹ Ifọ, ti wọn ti fun Ọlọfin Iṣhẹri laaye tabi agbara lati sọrọ tabi gbẹnusọ fawọn ọba alaye yooku, eyi to tumọ si pe yiyan ẹ yii ki i ṣe tẹwọgba awọn ọba yooku"

Wọn wa fikun ọrọ wọn ilu Agbado ni ọba, to wa ni ipo kin in ni, ti gbogbo ilu tẹwọgba iyẹn Ọba Adedayọ Shyllon, to si ti yan Iyalode labẹ ẹ, awọn ko si le gba Iyalode mii in laye lati ita.

Lakootan, wọn wa kede pe iyalode jẹnẹra ti wọn fẹẹ yan awọn ko fọwọ si, wọn wa lo akoko naa lati kesi ijọba ipinlẹ Ogun labẹ ileeṣẹ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ lati kilọ fawọn to n gbe igbesẹ ọhun nitori o le da wahala silẹ niluu.

Bẹẹ ni wọn rọ awọn araalu lati ma ṣe tẹti si gbogbo ikede ti wọn ni ko lẹsẹ nilẹ naa. Nitori Agbado jẹ ilu ti alaafia, isọkan ati ifẹ jọba ninu ẹ.

No comments:

Post a Comment

Pages