Ẹgbẹ oṣelu ADC ipinlẹ Ogun ba Jimi Lawal yọ lori bi INEC ṣe gbe orukọ ẹ jade - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 28 August 2026

Ẹgbẹ oṣelu ADC ipinlẹ Ogun ba Jimi Lawal yọ lori bi INEC ṣe gbe orukọ ẹ jade

Ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress,ADC,ipinlẹ Ogun ti rannṣẹ ikinni ku oriire si oludije Gomina wọn fun ibo to n bọ, Ọtunba Jimi Lawal atawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ijọba apapọ ati ti ipinlẹ ti ajọ eleto idibo INEC gbe jade.

Gẹgẹ bi atẹjade to tẹ wa lọwọ, eyi ti alaga ẹgbẹ naa Ọtunba Fẹmi Ṣoluade fi si, lo ti bawọn oludije ọhun dupẹ to si tun ki wọn ku oriire.

Bẹẹ ni wọn tun fi ọkan gbogbo awọn oludije yooku ti orukọ wọn ko tii jade ti wọn ṣe ibo alabẹṣekele wọn pẹlu Ọtunba Jimi Lawal tile ẹjọ giga fọwọ si pe ki wọn fọkanbalẹ pẹlu ileri pe gbogbo igbesẹ to ba yẹ ni ajọ INEC yoo gbe lati jẹ ki orukọ wọn jade laipẹ.

Ọtunba Fẹmi Ṣoluade waa sọ pe laipẹ yii lawọn yoo kede igbakeji Gomina fun Ọtunba Jimi Lawal.

O wa lo akoko naa lati fi ke si gbogbo ọmọ ẹgbẹ pe ki wọn tubọ wa ni ifẹ ati isọkan ati pe niru akoko bayii bi gbogbo wọn yoo ṣe wa papọ, ki wọn gbagbe awọn nnkan to ti ṣẹlẹ sẹyin lo jẹ wọn logun.

O tun mu dawọn oludije yooku loju pe ko ni si ẹnikan ti wọn ko nii gbe orukọ wọn jade laipẹ.

No comments:

Post a Comment

Pages