Ọga agba fawọn aṣọbode nipinlẹ Ogun Ọladapọ Kayọde Afẹni lo sọrọ naa lakooko ti wọn ṣiro iṣẹ irinju wọn fawọn oniroyin, eyi to waye ni oluuleṣẹ wọn to wa ni Idiroko.
O sọ pe awọn ti bẹrẹ lati maa ṣe itọpinpin awọn onifayawọ lawọn ẹnubode to paala kaakiri ipinlẹ naa.
Afẹni tun ṣalaye siwaju pe gẹgẹ bi owe Yoruba to sọ pe ojubọrọ kọ ni wọn fi gbọmọ lọwọ ekurọ, idi niyii tawọn fi jọ ni ajọṣepọ pẹlu awọn oṣiṣẹ alaabo yooku lati fi jọ gbogun tawọn onifayawọ yii.
O wa lo akoko ọhun lati kilọ fawọn onifayawọ lati fi tete tun ero wọn pa fawọn iṣẹ ti wọn ṣe, nitori ijọba ko nii foju idariji wo ẹnikẹni tọwọ ba tẹ.
Bẹẹ lo tun ṣalaye pe o kere tan biliọnu mẹta abọ naira lowo awọn ẹru ofin tawọn rii gba lọdọ onifayawọ.
Lara awọn ẹru ofin ti wọn ri gba naa ni baagi apo irẹsi ẹgbẹrun meji le ni ọọdunrun, ayederu irẹsi lati ilẹ Ghana toun jẹ ẹgbẹrun mẹfa o le, ayederu baagi apo ṣuga, kẹgi pẹtiroolu ati diisu.
Awọn yooku tun ni ayederu ọti, ogun oloro, aṣọ ati bata atawọn nnkan mii in. Afẹni fikun ọrọ ẹ pe akoba keker kọ awọn onifayawọ ko ba ọrọ aje wa, to si yẹ ki opin ti deba.
Lẹyin naa ni ọga aṣọbode ọhun wa fa awọn ogun oloro ti wọn gba le ajọ to n gbogun ti ogun oloro iyẹn NDLEA lọwọ.
O wa gba awọn ọba alaye, baalẹ atawọn araalu lapapọ lamọran lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn alaabo ki wọn le jọ gbogun tawọn onifayawọ ti wọn wa lagbegbe wọn.
Ninu ọrọ Wọle Fagboun ọga ajọ NDLEA lagbegbe idiroko lo ti dupẹ lọwọ Afẹni atawọn aṣọbode fawọn iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe, o waa ṣeleri atilẹyin to lagbara pẹlu wọn.
No comments:
Post a Comment