O tun fidi ẹ mulẹ pe anfaani nla ni yoo jẹ fawọn eeyan ni awujọ, nitori onírúurú oúnjẹ ni yoo wa nibẹ.
Lẹ́yìn ti aya Tinubu kuro nibẹ lo wa si Sagamu si Abeokuta, nibi ti wọn ṣi awọn ile kan ti Gomina Dapọ Abiọdun kọ si ọgba Buhari Estate, eyi to wa lọna Kọbapẹ.
Bẹẹ naa lo tun si ileewosan Gateway Medical Centre, nibẹ lo ti sọ pe awọn nnkan toun ri yii dun mọ oun ninu nitori awọn ohun elo igbalode ni, to si jẹ ohun ti yoo wulo fun itọju awọn ti wọn ba saisan ti wọn maa n gbe lọ siluu oyinbo fun itọju.
O fi akoko naa ke si awọn Gomina ipinlẹ kaakiri ilẹ Yoruba lati ṣe agbekalẹ iru nnkan bẹẹ.
Sẹnatọ Tinubu ṣapejuwe banki ounjẹ naa gẹgẹ bi ojutuu alailẹgbẹ si aisi ounjẹ, ni ibamu pẹlu eto Ireti tuntun ti Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ìyẹn Renewed Hope Agenda , eyi to da lori aabo ounjẹ, ilera, ati iranlọwọ awujọ.
Minisita fun eto ọgbin, Abubakar Kyari, ṣalaye awọn anfaani onírúurú ti ibudo oúnjẹ naa yoo ṣe fun awujọ.
Oni yàtọ̀ si pe yoo jẹ ki oúnjẹ pọ, yoo tun ṣe ìrànlọ́wọ́ fun awọn agbẹ lati pese ibi ti wọn yoo ma ta awọn ere oko wọn si.
Ko tan sibẹ, oni yoo tun ṣe ìrànlọ́wọ́ nla fun eto ilera nítorí awọn ohun ọgbin ti ko le ṣe ipalara fun eto ilera ara ni yoo ma wa ni ibudo naa.
Kyari ni ifilọlẹ ibudo oúnjẹ yii ṣe afihan ìlọṣíwájú lori eto oúnjẹ nipinlẹ Ogun.
No comments:
Post a Comment