Ninu atẹjade kan to gbe jade eyi to pe akọle ẹ ni 'Ẹru olori oṣiṣẹ aarẹ, idi ti didakẹjẹ fi maa n mu aṣiṣe wa'
O sọ pe ni ọpọ iṣejọba, oriṣii awọn ẹka lo maa n dara ti wọn gboriyin fun bẹẹ lo ni awọn kan wa tawọn aye maa n foju si lati bu ẹnu atẹ lu tabi fura sii.
O ni lara eyi ti ẹru maa n pọ lori ẹ ju ni ti olori awọn oṣiṣẹ aarẹ. O ni bo tilẹ jẹ pe ipo ọhun lagbara ninu ijọba amọ sibẹ o jẹ eyi tawọn araalu ko fi bẹẹ ni agbọye lee lori.
Ọtunba Ṣowunmi tun fikun ọrọ ẹ pe ẹni to gbọdọ wa lori ipo naa gbọdọ jẹ ẹni gbọdọ mọ nipa iṣejọba, oṣelu, aabo ati ipinnu aarẹ.
O ni, " O gbọdọ jẹ ẹni ti yoo maa ja fun ileeṣẹ aarẹ lati ma jẹ ki epo aala ta si iṣejọba to ba n lọ lọwọ.Gbogbo bi nnkan ba ṣi ṣe n lọọ ni yoo ri pe araalu maa mọ, oun ni yoo si maa wa lori iṣakoṣo awọn nnkan to ba nii ṣe pẹlu aarẹ.
" Ibi ẹru wuwo yii ni Oloye Fẹmi Gbajabiamila ba ara ẹ lakooko yii.Gẹgẹ bi agba oṣelu, to ni iriri, to ti jẹ olori ọmọ ile igbimọ aṣoju ṣofin lorileede yii, to si ti lo ọpọ ọdun nidii iṣẹ ijọba, to si ti di awọn ipo to lapẹẹrẹ mu lawujọ.
Ṣowunmi ni ohun ti ko dara ti ko lẹtọọ ni ki wọn ma polongo ahesọ ọrọ lati sọ ọ di ootọ.
O ni loootọ awọn araalu tete maa n da eeyan lẹbi ti wọn ba gbọ pe wọn fẹsun kan ni,lai tiẹ beere tabi ṣewadii iru ẹsun bẹẹ
"Ọpọ awọn eke adugbo yoo ti gba gẹgẹ bi iṣẹ, ti wọn yoo maa fun ni oriṣii akọle bẹẹ lawọn ti ori ẹlẹrọ ayelujara yoo sọ ara wọn di oluwadii apapandodo.
"Wọn yoo wa fẹ ki ẹni ti wọn fẹsun kan ko waa wi awijare nita gbangba lori awọn nnkan ti wọn hun pọ, ti ootọ le ma si nibẹ. Ṣugbọn wọn ki i ṣejọba bẹẹ.
" Ọfiisi olori oṣiṣẹ kii ṣe fọrọ oṣelu, ko wa lati ma gba ọrọ bi ẹni gba igba ọti lori ẹrọ ayelujara.Ileesẹ to nii ṣe pẹlu aarẹ ni.
O ni nitori ki i ṣe nnkan to ba n lọ nibẹ ni wọn gbọdọ maa sọ fun araalu.Gbogbo nnkan ti wọn ba pinnu kọ lo yẹ ki wọn gbe sori ayelujara.
Oludasilẹ ẹgbẹ 'The Alternative' wa sọ pe didakẹjẹ ti wọn maa n dakẹ lo fi aaye tawọn agbọyisọyi fi n sọ oriṣii.
O ni kekere ni awọn araalu n ri ṣugbọn afojusun wọn pọ. O sọ pe awuyewuye to n da wahala silẹ yii ti wa nile ẹjọ bẹẹ ni ajọ to n ri si ṣiṣowo ilu kumọkumọ iyẹn ICPC naa ti ṣiṣẹ iwadii wọn lee lori pẹlu.
O ni ti ifẹsun kan ni ba waye, dandan ni ki wọn ṣewadii lati ri okodoro, bẹẹ lo ni ti ede aiyede ba ṣèlẹ, iṣẹ ile ẹjọ ni lati ṣedajọ to yẹ.Bakan naa ti ọrọ baa fẹẹ ruju, ẹri gbọdọ wa pẹlu.
O fikun ọrọ ẹ pe ohun to ṣe pataki ni pe ijọba ko le fọwọ si ahesọ tabi ẹsun ti ko fẹsẹmulẹ niwọngba ti ko ba ti si ẹri to le gbe e lẹsẹ..
Laakotan, o ni ẹru to wa ni ẹka olori oṣiṣẹ aarẹ ki i ṣe kekere bẹẹ ni ki i ṣe ti agbara to jẹ pe gbogbo nnkan to ba n lọ nibẹ ni wọn gbọdọ maa sọ faraye gbọ.
No comments:
Post a Comment