Ọpẹ o! Ile ẹjọ ni Jimi Lawal ni ojulowo oludije Gomina fẹgbẹ oṣelu ADC nipinlẹ Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 23 July 2026

Ọpẹ o! Ile ẹjọ ni Jimi Lawal ni ojulowo oludije Gomina fẹgbẹ oṣelu ADC nipinlẹ Ogun

Ile ẹjọ ijọba apapọ to wa niluu Abẹokuta ti gbe idajọ ẹ kalẹ pe Ọtunba Jimi Lawal ni ojulowo oludije Gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC pẹlu aṣẹ pe ki ajọ eleto idile iyẹn INEC, tete fi orukọ ọkunrin naa si awọn oludije ibo ọdun to n bọ.

Idajọ ti Onidajọ Abiọdun Jordan Adeyẹmi gbe kalẹ yii ni yoo fopin si gbogbo wahala to ti n waye ninu ẹgbẹ ọhun, eyi to jẹ ki wọn pin si igun.

Nibi ẹjọ kan ti nọmba ẹ jẹ FHC/AB/CS/97/2026 ni wọn ti pe ẹjọ lori wahala to waye lakooko ti wọn dibo alabẹsekele ẹgbẹ ọhun ninu eyi ti wọn ti yan awọn oludije gomina lọna meji.

Onidajọ Adeyẹmi sọ pe bi a ba ni ka sọ ododo nilana ti ofin la kalẹ nipa eto idibo alabẹsekele ọhun ibo to gbe Lawal ni ojulowo nitori awọn ajọ INEC  ni wọn wa ṣabojuto ibo naa.

O ni bigba ti wọn ba fi akoko ṣofo ni ẹni yoowu to ba gbe oludije mii in kalẹ fun ipo gomina.

O waa pa a laṣẹ fajọ eleto idibo INEC lati ṣe gbogbo ohun to ba tọ to si yẹ fun Jimi Lawal gẹgẹ  bi ofin ba ṣe gbe e kalẹ.

Nigba to n sọrọ lẹyin idajọ, alaga fẹgbẹ oṣelu ADC  nipinlẹ Ogun, Ọtunba Fẹmi Ṣoluade, fi idunnu ẹ han lori idajọ naa.

O ni akoko ti wa to bayii ki gbogbo wọn jọ wa niṣọkan lati ṣiṣẹ pọ fun igbelarugẹ ẹgbẹ naa.


No comments:

Post a Comment

Pages