Ẹgbẹ́ awon oniroyin ede Yoruba, iyen 'League of Yoruba Media Practitioners' (LYMP) ti fi oye baba egbe naa da agba oloselu ati akinkaju omo Yoruba, Oloye Olabode Ibiyinka George lola. Ojoruu, Wesidee to koja yii leto idanilola ohun waye.
Egbe naa se eyi fun mimo riri ati atileyin ti baba fun egbe yii ati fun iran Yoruba lapapo.
Ọ̀pọ̀ àwọn àlejò ló péjọ síbi idalola naa, eyi ti ko yo awon omo Oloye Bode George sile, bee lawon omo egbe 'League of Yoruba Media Practitioners' naa wa nikale lati ye baba naa si
Lasiko to n gbe ami idalola naa fun Oloye Bode George, Ààrẹ ẹgbẹ́ náà, Olaide
Gold, so pe gbogbo egbe lo fenuko lati fi agba oloselu naa se baba egbe won nitori ipa nla ati atileyin ti ko legbe ti baba naa se fun egbe yii.
Nígbà tó ń gba oyè náà, Oloye Bode dúpẹ́ gidigidi fún ọlá tí wọ́n bu fún un yii. o sì ṣèlérí pé òun yoo lo gbogbo agbára to wa nikapa oun lati satìlẹ́yìn fún ẹgbẹ́ náà, ki ede Yoruba ati aṣa wa le tunbo gbayi si i kari aye.
Ohun to daju saka nipe titi aye ni Oloye Bode George yoo maa ranti ohun tawon omo egbe 'League of Yoruba Media Practitioners' yii se fun un.
No comments:
Post a Comment