Ileewe kọlẹẹji Favour Comprehensive gba ife ẹyẹ idije bọọlu Afẹni. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 26 July 2026

Ileewe kọlẹẹji Favour Comprehensive gba ife ẹyẹ idije bọọlu Afẹni.

Ileewe kọlẹẹji Favour Comprehensive lo jawe olubori nibi idije ife ẹyẹ ere bọọlu ti wọn fi sọri ọga agba ajọ aṣọbode nipinlẹ Ogun, Ọladapọ Ksyọde Afẹni.

Idije ọhun to waye lopin ọsẹ to kọja yii nileewe ọhun ti gba ife ẹyẹ. Ọga agba aṣọbode, Afẹni at ileewe Jonneyeco College of Health Scince of Technology, lo ṣagbatẹru idije ọhun fawọn ileewe to wa lagbegbe Idi Iroko.

Awọn ileewe mejila la gbọ pe wọn kopa nibi idije ọhun. Nibi aṣekagba idije ọhun ni ọga agba aṣọbode ọhun ti ṣalaye idi pataki ti wọn fi ṣagbatẹru idije ere bọọlu naa.

O ni eyi yoo jẹ ki wọn ṣawari ẹbun ere bọọlu gbigba lawọn agbegbe Idiroko ati pe yoo tun fi aye silẹ lati ma dawọn ọdọ lẹkọọ lọna igbogun ti iṣẹ fayawọ  ni ṣiṣe.

Fun odidi ọsẹ meji ni idije ere bọọlu ti waye nibi tawọn agbabọọlu ọmọleewe ti wa fẹbun wọn han bẹẹ lo ṣe jẹ pe awọn onworan atawọn oloolufẹ ere bọọlu fi gbogbo akoko naa fun oju lounjẹ.

Bakan naa lawọn to gba bọọlu wọle daadaa naa tun gba ẹbun,  ẹni to mọ ilu mu iyẹn  goolikia naa tun mu ẹbun lọ sile pẹlu.


No comments:

Post a Comment

Pages