Igbega ati Idagbasoke agbegbe Ifọ Keji jẹ mi logun ti mo ba wọle sile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun-Agnes Funshọ Akinlẹyẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 29 July 2026

Igbega ati Idagbasoke agbegbe Ifọ Keji jẹ mi logun ti mo ba wọle sile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun-Agnes Funshọ Akinlẹyẹ


Arabinrin Agnes Funshọ Akinlẹyẹ, oludije fun ipo ọmọ ile igbimọ aṣofin ẹkun ifọ keji labe ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress, NDC, nipinlẹ Ogun ti sọ pe bi igbega ati idagbasoke yoo fi tubọ ba agbegbe toun ṣoju fun lo ṣe pataki foun.

Obinrin naa sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ laipẹ lori erongba ẹ to ba wọle ninu ibo ọdun to n bọ naa.

Gẹgẹ bo ṣe wi, agbegbe Ifọ Keji kọja nnkan tawọn eeyan le foju bintin wo, idi niyi to fi jẹ pe ẹni to ba ṣoju wọn gbọdọ maa mu igbe aye irọrun bawọn olugbe to wa nibẹ.

O ni bo tilẹ jẹ pe iṣẹ awọn aṣofin ni lati ṣe awọn ofin to le inu awọn araalu dun ti wọn yoo fi mọ mudunmudun to wa ninu ijọba tiwa-n-tiwa.

Funshọ ṣalaye siwaju pe, "Loootọ ni mo jade lati dupo ọmọ ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun labẹ ẹgbẹ oṣelu NDC, eyi ti mo gbadura pe Ọlọrun yoo ran mi lọwọ lati debẹ gẹgẹ bi aṣoju rere fawọn eeyan mi.

"Ṣugbọn mo mu dawọn eeyan mi loju pe bi ilọsiwaju ati idagbasoke yoo ṣe de bawọn ni maa mu ni ọkunkundun."

O ṣalaye pe ọpọ awọn eto loun ni fawọn eeyan Ifọ Keji ti yoo mu irọrun ba wọn, paapaa lati wa ọna abayọ sawọn iṣoro to n doju kọ wọn.

Oludije NDC ọhun wa lo akoko naa lati rọ awọn obinrin akẹgbẹ ẹ lati dide gbaruku ti oun lati le jawe olubori ninu ibo ọhun pẹlu ileri pe oun ko ni jawọn nitanmọ.

O sọ pe gbogbo wa la mọ pe akoko ipolongo ko tii bẹrẹ, nitori idi eyi loun ko ṣe tii le mẹnuba awọn nnkan to ni lọkan fawọn araalu.

Bẹẹ lo tun fi idunnu ẹ han lori bi ẹgbẹ oṣelu NDC, ṣe fojoojumọ gbilẹ si nipinlẹ Ogun pẹlu idaniloju pe awọn ni yoo jawe olubori ninu ibo ọdun 2027.

 O ni ẹgbẹ NDC ti gbogbo araalu ni, Ọlọrun fẹẹ lo lati gba awọn eeyan kuro ninu ijọba to wa lode yii, nipasẹ ibo ọdun to n bọ naa.

No comments:

Post a Comment

Pages