O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ, o sọ pe ebi n pa awọn eeyan, ilu ko rọgbọ, oore ọfẹ lawọn eeyan fi wa laye. Bẹẹ lo ni eto aabo tun mẹhẹ, gbogbo ẹ ko ye araalu mọ.
O ni ero awọn araalu ni pe Aarẹ Tinubu yoo le ṣe ni, gbogbo wọn nigbagbọ pe o le ṣe, nitori ọpọ rii gẹgẹ bi ẹni ti oye ijọba tiwa-n-tiwa ye, to ti ṣe NADECO ati gbogbo ẹ, ṣugbọn o sọ pe nigba to de bẹ, ofo ni.
O ni latigba to ti de bẹ ilu ko rọgbọ, Ọlọrun ni kan lo le ṣaanu lorileede yii, idi niyii lo fi sọ pe idaniloju wa pe NDC, ti Peter Obi, jẹ oludije wọn fun ipo aarẹ yoo jawe olubori.
Alaga ẹgbẹ ọhun tun ṣalaye pe nipa eto aabo, ki i ṣe ipinlẹ Ogun nikan, orileede yii lapapọ, ohun to ba ti ba oju, o ti ba imu. Ko rọgbọ, ko dara,ko ṣe e tẹwọgba.
O ni, "A fi kawọn olori to wa nibẹ ṣatunṣe, nitori a n ṣe oṣelu, ko yẹ ka fọmọ, ara wa ẹmi wa ṣe e, ẹ wo awon ọmọleewe atawọn olukọ wọn ti wọn jigbe bii oṣu meji, a fi ki Ọlọrun ṣaanu wa. Ko ba wa da si ọrọ orileede lati gba wa lọwọ awọn aninilara to wa nijọba".
Nigba to n mẹnuba ẹgbẹ oṣelu NDC nipinlẹ Ogun, Fẹmi Alao sọ pe, "Ẹgbẹ tuntun ni a le pe NDC tẹlẹ nipinlẹ Ogun, amọ ni bayii, ki i ṣe bẹẹ mọ, Nitori bi oṣu meloo kan ṣẹyin lawọn eeyan gbọ hulẹhulẹ nipa ẹ.
"Amọ bi oṣu kan si akoko yii, ariwo okiki ẹgbẹ ọhun ti tan kalẹ, o ti di eyi to n bawọn to wa nibẹ lakooko yii dije fawọn ipo kaakiri. O ti gbooro bẹẹ lo tun ti gbilẹ nipinlẹ Ogun.
Bẹẹ lo tun sọ pe"Awọn aṣeyọri to maa n de ba ẹgbẹ ni, ta a ba n ri awọn eeyan lọtun losi lati wọọdu titi de ipinlẹ, ti wọn wa n darapọ aṣeyọri to lagbara ni.
"Nitori pe awa gan an ko mọ pe a le gbilẹ to bayii, to fi di pe ojoojumọ la n gboro sii.Lati bi oṣu meji sẹyin ni ṣa a n gba ipe tawọn eeyan fifẹ han lati darapọ mọ NDC.
"Igba ti Obi ati Kwankwaso ti de ni ẹgbẹ naa ti gbilẹ gan an ni.Mo si le fọwọ sọya pe ẹgbẹ oṣelu NDC ti n bo orukọ ẹgbẹ kan to ti wa nilẹ tẹlẹ lọ nipinlẹ Ogun.
O ṣalaye siwaju pe ẹgbẹ wọn ti wa nimurasilẹ fun ibo to n bọ lọdun 2027. Laipẹ yii lawọn ṣe ipade gbogboogbo fawọn oloye ẹgbẹ lati wọọdu de ipinlẹ.
Lẹyin naa lawọn tun ṣe ibo alabẹsekele iyẹn pamari fawọn to fẹẹ dije dupo fun ibo to n bọ lọna naa. Koda awọn ajọ eleto idibo iyẹn INEC ni wọn wa salamojuto.
O ni, "Mo fẹẹ mu da yin loju pe gbogbo awọn oludije wa lati ọmọ ile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja, Aṣoju- ṣofin, ọmọ ile igbimọ aṣofin tipinlẹ to fi dori gomina ni wọn wẹ ja kainkain ti wọn kun oju oṣuwọn.
"Awọn ibi kan wa tawọn oludije jọ ja dupo ṣugbọn ti wọn yanju ẹ laarin ara wọn, ki ẹ le mọ bi ẹgbẹ wa ṣe lagbara to.
"Nipinlẹ Ogun, awọn araalu ti ṣetan lati yan olori tuntun, koda ipinlẹ yii nikan kọ, ni orileede lapapọ.
Nigba to n sọ nipa Peter Obi, oludije wọn fun ipo aarẹ, nipa bo ṣe mọ ọn, ọkunrin naa ni, "Ohun ti mo ri lara ẹ ti mo fi tẹle gẹgẹ bi oludije aarẹ orileede yii, o jẹ ẹni ti ko nimọ tara ẹni, ko si ẹgbẹ oṣelu to lọ tawọn eeyan ko ni sọ pe awọn ko nii mu.
"lṣejọba ẹ yatọ nigba to fi jẹ gomina, ko ṣejọba apo ara ẹ, lakooko naa bawọn kan ṣe si ọfiisi fun Iyawo wọn, ko ṣe e ni tiẹ.
"Bi ẹẹmẹta ọtọọtọ ni mo ti ba a pade ninu baalu, ko bawọn fi owo Ijọba ṣofo, o ni iwa ọmọluabi lara. Idi niyii tawọn araalu fi n fẹ ko di aarẹ.
"Ẹru Ọlọrun ba mi gan an ni, nitori latigba to ti denu ẹgbẹ yii, ojoojumọ lawọn eeyan n darapọ. Ti wọn n pe mi nipinlẹ Ogun, nitori wọn ti ri iwa ọmọluabi lara ẹ. Wọn ti rii gẹgẹ bi ẹni to le tun orileede yii ṣe".
Alaga ọhun wa sọ pe ki a maa gbowo lọjọ idibo, ki n ṣe nnkan to tọna, ati pe nibi taa ba ara wa lorileede yii niyẹn.
O ni ko sẹni ti wọn ba fun lowo ti ko nii gba, ko sẹni ti ko fẹran owo. A ni ki wọn ma gba owo, ṣugbọn ki wọn dibo fun ẹri ọkan wọn, ẹni ti wọn mọ pe yoo tun ilu ṣe ti yoo mu irọrun ba wọn.
No comments:
Post a Comment