Ẹ jẹ ka ṣi maa farada bi nnkan ṣe n lọ lorileede yii- Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 24 July 2026

Ẹ jẹ ka ṣi maa farada bi nnkan ṣe n lọ lorileede yii- Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun

Oludaisi Oluṣẹgun Ẹlẹmide, olori ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun ti rọ gbogbo ọmọ orileede yii pe ki wọn tubọ si maa farada bi nnkan ṣe lọ lorileede yii nireti pe ọjọ iwaju n bọ wa dara.

O sọrọ yii nigba to n ba awọn akọroyin Yoruba sọrọ laipẹ yii, gẹgẹ bo ṣe wi, o ni o dara ki eeyan koju ipenija lẹẹkan ṣoṣo, ko si wa ọna abayọri sii, ju pe ko ma ṣe daku daji lee lori.

O ni ọpọ idojukọ wa lakooko yii paapaa julọ lori ọrọ aje ati eto abo nnkan taa le wa iyanju si ni pẹlu afojusun ọjọ iwaju.

Bakan naa lo sọ pe afọwọfa awọn mi-in lo maa n jẹ ki wọn kagbako ikọlu awọn ajinigbe. Iyẹn nipa eto abo.

Olori ile igbimọ aṣofin ọhunni "Bi ẹlomi-in ba n wọ baalu lọ si Abuja, yoo ya fọtọ lẹgbẹẹ baalu, yoo waa gbe e sori ẹrọ ayelujara pe ọna Abuja loun wa bayii. Iru awọn eeyan bẹẹ ni wọn n polongo ara wọn fawọn ajinigbe.

"Nigba ti eeyan ba lowo, ti ko fi owo to ni ran awọn alaini lọwọ, to waa jẹ pe niṣe lo n fi owo to ni yangan ṣi gbogbo aye, bi wọn ba ji iru eeyan bẹẹ gbe, ṣe oun kọ lo fọwọ ara ẹ fa a?"

O wa ni bi a ba ni ka sọ ododo ko yẹ ki awọn aṣofin Naijiria  jokoo tí ofin ṣiṣe gẹgẹ bii iṣẹ oojọ wọn, owo ijokoo ti wọn  ba jokoo nIleegbimọ aṣofin nikan lo yẹ ki wọn maa gba.

O ni eyi yoo dín inawo ijọba ku, yoo si fun awọn aṣofin lanfaani lati tẹsiwaju ninu iṣẹ ti wọn ba n ṣe tẹlẹ ko too di pe wọn dibo wọle sileegbimọ aṣofin.

O ni iṣẹ to daa ju fawọn aṣofin lati maa ṣe ni iṣẹ agbẹ, lati jẹ ki ounjẹ sun awọn ọmọ orilẹ-ede yii bọ.

Nipa wahala laarin awọn agbẹ atawọn Fulani darandaran, olori awọn aṣofin ipinlẹ Ogun yii sọ pe Ileegbimọ aṣofin ipinlẹ naa ti ṣofin tako ki awọn eeyan maa da maalu jẹun kiri inu oko oloko, o waa ku ṣọwọ awọn agbẹ lati maa fi ẹjọ awọn arufin naa sun awọn agbofinro nigbakuugba tí awọn onimaalu ba fi maalu jẹ ohun ọgbin wọn.
  
O ni, "Iṣẹ to wu mi lati maa ṣe pẹlu iṣẹ aṣofin ni iṣé agbẹ. 

 "Nitori pe agbegbe ti mo n ṣoju ko tii ri bi mo ṣe fẹ ni mo ṣe tun fẹẹ dupo yii lọdun 2027 lati tẹsiwaju ninu ohun ti mo n ṣe lọwọ, iyẹn ti awọn eeyan ba fun mi loore ọfẹ nitori kii ṣe dandan ni wọn fi n ṣiṣẹ sin ilu."

No comments:

Post a Comment

Pages