Awọn to n sọ ahesọ kaakiri ilu Iroko ko lẹnu nibẹ, ẹri ọkan lo n ti wọn kiri. Bẹẹ ni mo tun gboriyin fun Aarẹ Tinubu- Oniroko - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday, 20 July 2026

Awọn to n sọ ahesọ kaakiri ilu Iroko ko lẹnu nibẹ, ẹri ọkan lo n ti wọn kiri. Bẹẹ ni mo tun gboriyin fun Aarẹ Tinubu- Oniroko

Nitori ahesọ ọrọ ti wọn lawọn kan niluu Iroko, nijọba ibilẹ Ado-Odo- Ọta, nipinlẹ Ogun, n sọ kaakir lati fi tabuku ọba wọn,Ọba Oluṣẹgun Ayinde Feyijinmi, Oniroko tiluu iroko. 

Ọba naa ti sọ pe ko si ootọ kankan ninu ọrọ naa ati pe ọpọ wọn ni ki i ṣe ọmọ bibi ilu ọhun ti wọn fẹẹ maa halẹ mọ ọmọ onilu.

O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ lori idagbasoke to ti deba ilu naa lati bi ọdun meje abọ sẹyin.

O sọ pe awọn ti wọn sọrọ yii ko lẹnu nibẹ ati pe ẹri ọkan iwa ibi ti wọn ṣe siluu lo dawọn laamu kaakirii.

O ni gẹgẹ bi ọba alaye ati olori ilu, ohun to ṣe pataki lọkan oun to si maa n wa niwaju oun nibi ilu Iroko yoo ṣe tẹsiwaju ninu idagbasoke ti wọn yoo si wa loke laarin awọn ilu yooku.

Kabiyesi sọ pe ẹni to ba n fẹ ilọsiwaju ko gbọdọ boju wẹyin nitori ko si ki awọn ọbayejẹ eeyan ko ma si.

O ni, "Ko le ma ri bẹẹ,ti nnkan ba n dun, to n dun, ti ko si ọta,alatako,ọlọtẹ, ẹ sọ fun onitọhun ko yẹra ẹ wo. Nitori eeyan ko le da a tan laye yii.

"Nnkan to ba ti dara, ọpọ eeyan lo maa n hu, amọ ọpọ kọ lọ tọ si,a ko le rin, ki ori maa mi. Bi mo ṣe wa niluu Iroko,ilu baba to bi baba mi ni.ti mo n wi bẹẹ, tawọn alaalẹ si n jẹ ko ri bẹẹ.eeyan ko le daa tan, iwọnba lo le ṣe.

"  Kin ni mo tun n fẹ, mo n ri atilẹyin latọdọ ọpọ araalu, gbogbo awọn abinibi ọmọ Iroko, aafin ni wọn ti n ṣe ipade, gbogbo ẹgbẹ idagbasoke niluu yii ẹyin m ni wọn wa.

"Mo ti sọ laimọye igba pe ẹni tinu ba n bi ki wọn lọ si kootu, ki wọn si mu ẹri jade, titi di akoko yii to n lọ si ọdun kẹjọ ti mo gori oye, a ko ri ẹnikẹni, ko sẹni to nigboya.

" O waa ni bawo ni alejo kan yoo ṣe fẹẹ yi itan oun pada, wọn ko le mọ ọn to oun ati pe ija ilara lo n ba wọn ja, oun si fa wọn le Ọlọrun lọwọ.

Nigba ti Oniroko ṣalaye bo ṣe n ṣeto abo ilu ẹ, O sọ pe, " Gbara ti mo ti gori itẹ awọn baba mi, ni mi o ti feto abo ṣere ṣere pẹlu awọn eeyan mi. Idi niyii taa fi kọ ileeṣẹ ọlọpaa.

"Bẹẹ ni a tun maa n ṣe ipade loorekoore pẹlu olori ẹgbẹ awọn agbegbe iyẹn CDA, awọn baalẹ,olori awọn Hausa ati Ibo ti wọn wa niluu lati le mọ ibi ti aabo duro de bẹẹ la st tun maa n forikori lati wa ọna abayọ sawọn ibi to ba ku diẹ kaato.

"Ohun taa si maa n jẹ ko ye wọn ni pe loootọ ọmọ Naijiria ni wa ṣugbọn a ko le gba ki ilu Iroko ba jẹ"

Ọba Feyijinmi iroko tun sọ pe, "Nigba tọrọ ijinigbe tun gbilẹ a pe awọn Hausa ati Ibo si ipade pe wọn gbọdọ fun wa ni olori kan, nitori ti nnkan ba ṣẹlẹ niluu oun ni wọn yoo lọ ba.

Laipẹ yii lo ni wọn fi ọkan lara awọn Hausa jẹ Ṣeriki, tawọn siwadii ẹ daadaa ko to di pe wọn fi joye.

Iyẹn nikan gbogbo awọn Hausa ati Ibo to wa niluu ni wọn ti gba fọọmu, ti wọn si ti buwọ luu gẹgẹ bi iwe adehun tawọn olori wọn si ti fọwọ si pẹlu.

Oniroko tiluu Iroko wa gboriyin fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, lori idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ, ẹyi to ti niwaju ile igbimọ aṣofin to gaju lọ niluu Abuja.

O ni igbesẹ to dara ju ni, ti yoo mu ki eto abo tun gbilẹ si lorileede yii. O waa ki wọn fun ọkan akin oṣelu ti wọn ni lati gbesẹ bẹẹ.
O ni, " Mo gboṣuba o kare fun Aarẹ wa, nitori pataki ni aabo ko lorileede yii, bi ko ba si aabo, bawo la ṣe fẹẹ ṣe e.

"A gbọdọ mu aabo wa sibi to kere lati ipinlẹ de ijọba ibílẹ ati lawọn wọọdu kaakiri to fi de ọdọ awọn ọbalọba nitori awọn ọba lo mọ eeyan agbegbe ẹ.

O ṣalaye siwaju pe wọn gbọdọ fun awọn ọba laaye lati nipa pataki ninu ofin ọlọpaa ipinlẹ, nitori ilu kọọkan lo mọ bo ṣe n ṣe aabo ilu ẹ.

Kabiyesi ni, "A fẹẹ ki wọn fawọn ọba alade nipa pataki lati ko ninu ofin ọlọpaa ipinlẹ, nitori ilu kọọkan lo mọ bi wọn ṣe n ṣe aabo ilu wọn, ti wọn ni awọn bii Jagunmolu, Oluọdẹ,Akọgun gẹgẹ bi alaabo ibilẹ, iru awọn wọnyin ki wọn fun wọn laaye lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ọlọpaa ipinlẹ".


No comments:

Post a Comment

Pages