Ayẹyẹ ọhun lo waye ni olu-u-le-ẹgbẹ wọn to wa ni Arinlẹsẹ, niluu Abẹokuta. Nibẹ lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ọhun ti wọn le ni ẹgbẹrun ti peju pesẹ.
Ninu ọrọ ti Adenuga sọ pe oun gba lati dije lo ti kọkọ dupẹ lọwọ gbogbo ẹgbẹ fun anfaani ti wọn fun lati dije.
O ni oun gbaa gẹgẹ bi ifarajin lati sin awọn ara ipinlẹ Ogun ati lati mu atunṣe ba a. O wa bẹbẹ lati jọ dojukọ iṣoro ipinlẹ naa nipasẹ iwadii toun atawọn ikọ oun ti ṣe lati bii ọdun mẹrindinlogun sẹyin.
Adenuga tun ṣalaye pe erongba mi lati dije ki i ṣe lati tẹmbẹlu awọn to ti n ṣe ijọba bọ bi ko ṣe lati tubọ wa ojutu si ipenija ati idojukọ to n de ba wọn nipinlẹ Ogun ati orileede yii.
O ni awọn erongba lati mu idagbasoke wa jẹ eyi to nitẹwọgba lapapọ ti yoo si jẹ aṣeyọri fun ipinlẹ Ogun, iyẹn ti wọn ba le gba a wọle.
Oludije Gomina yii sọ pe o ti le ni ọdun meloo sẹyin tawọn erongba rere yii ti wa lọkan oun ati pe akoko ti to bayii ti yoo di mimuṣẹ nipinlẹ Ogun.
O loun gba lati dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu BOOT, bo tilẹ jẹ pe lati bi ọdun mẹrindinlogun sẹyin, loun ti n wa ọna abayọ si iṣoro awujọ.
O wa dupẹ lọwọ Ọlọrun fun oore ọfẹ toun ri gba lati bẹrẹ ẹ nipinlẹ Ogun.
No comments:
Post a Comment