O sọrọ nibi ifọrọwerọ to ṣe pẹlu oniroyin wa, o sọ oun to jẹ pataki foun ni lati sọ awọn eeyan di ominira, ki wọn si maa fojoojumọ wa ninu idunnu.
O ṣalaye pe ẹgbẹ tuntun lẹgbẹ wọn ati pe omi tuntun ti ru ẹja tuntun si ti wọ, oun ṣetan lati ṣejọba gẹgẹ bi ofin ba ṣe la kalẹ.
Ọnarebu naa to tun jẹ agba oṣelu nipinlẹ Ogun tun sọ pe "Ẹgbẹ ADC ni mo wa tẹlẹ, emi ni igbakeji akọwe iṣuna lapapọ fun ẹgbẹ naa, ṣugbọn nigba ti Peter Obi ti lọ si NDC ati Alaaji Kwankwaso, ni awa naa ti sọ pe o dabi pe ibi ti ọna yoo wa niyẹn.Ijọba to jẹ pe a le tu gbogbo araalu lara.
"Irẹwẹsi ọkan pe wọn fẹẹ yọ orukọ ẹgbẹ oṣelu NDC, ko le ba eeyan, nitori nnkan ti Adajọ yẹn ṣe ku diẹ kaato. O o le ṣe ẹjọ
ko pari ẹ, ko jẹ pe iwọ naa ni waa jokoo le lori.
"Iwọ to sọ pe adegun ko tun wa sọ pe adeogun mọ, awọn to sọ pe wọn gbe ẹjọ wa ba ẹ, ajọ eleto idibo ti ro ẹjọ wọn to jẹ pe iwọ yii naa lo jokoo le lori, to si ti gbogo fun NDC.
"Ati pe awọn wọnyii nibo ni wọn wa nigba ti wọn ṣẹjọ. O ṣe jẹ pe igba ti akoko lọ ni wọn wa n wa.
"Kilode ti wọn ko ṣe lọ sile ẹjọ to gaju lọ, ki wọn lawọn fẹẹ fagile? Kilode to fi jẹ pe ọdọ ẹ ni wọn wa, lo ṣe jẹ kawọn eeyan maa roo pe nnkan wa nidii ẹ'.
Bakan naa ni Ọnarebu Geoge-Taylor, tun mẹnuba idi pataki to fi nii lọkan lati jade dupo labẹ ẹgbẹ oṣelu NDC, nigba to sọ pe, "Ṣe ri ọrọ ṣenetọ ti mo jade fun un, lati aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, a n wo bi nnkan ṣe lọ, a si n foju woo pe awọn to wa nibẹ, kin ni anfaani tawọn araalu gba lọdọ wọn?.
"Oju ti awa fi n ri wọn bii ka kẹyin jẹ tan, ka pa adiẹ, wọn wo awọn eeyan bi ẹni pe oju egbo wọn ko jinna, wọn tun wa ki igi bọ ọ loju.
"Ẹ wo ipinlẹ Kogi, nnkan ti Sẹnetọ Natasha, ṣe fawọn eeyan ẹ, awọn ti wa nibi, kin ni a ri?, afojusun wọn ni pe ti akoko ibo ba to, awọn tawọn ri, ki wọn tun lọ da agbado silẹ fun wọn, tawọn ba ṣe bẹẹ, wọn ṣa maa jẹun.
"Ki a tun wa ri eeyan ko sọ fun wa pe gbogbo nnkan gbọdọ lọ leto leto bi Peter Obi, asiko ti de lati di ominira, to ma
tutu mọ eeyan ti wọn yoo fi ni ilọsiwaju.
"Ọpọ awọn nnkan lo wa ninu ipo sẹnetọ, gbogbo nnkan tijọba ba ṣe lo n gba ọdọ awọn aṣofin kọja.Ko si nnkan to le mu idagbasoke, idẹrun ati ilọsiwaju ba araalu ti ko ni gba ọdọ wọn kọja.
"To ba dele igbimọ aṣofin to ranti awọn eeyan rẹ, o ko kawọn kun naa ni. Ohun to wa lọkan wa ni pe iya to ti jẹ awọn araalu,atunṣe nla yoo de ba a.
"Ki awọn eeyan le ri ominira gba pẹlu idunnu ati ifọkanbalẹ ninu ile onikaluku wọn.
Nigba to n sọrọ nipa igbaradi ẹ pẹlu awọn oludije ti wọn jọ wa lati ẹkun kan naa, o sọ pe, "Ibo to wa nilẹ lọtẹ yii fọwọ ara ẹ ṣe ara ẹ ni o, to ba ṣe pe bi wọn ṣe n ṣe lo tẹ ẹ lọrun, tete lọ dibo fun wọn.
"Emi rooo pe bi o wa nibi kan fọdun mẹrin ti wọn na ẹ ni kondo nibẹ, ti wọn tun ṣe bẹẹ fun ẹ lọdun mẹrin mii-ii, to ba tun wa lọ tẹle wọn, a jẹ pe iya lo tọ si ẹ.
"Asiko lati ronu ree PDP naa ti ṣe ti wọn, wọn ti ṣee ri.NDC ta a wa ninu ẹ, ẹgbẹ tuntun ni, omi tuntun ti ru, ẹ gba rukutu ti wa. Inu yin a dun kalẹ, gbogbo nnkan yoo di ominira.
O tun sọ pe ohun to ma n jẹ ki ẹgbẹ rinlẹ ni owo ti wọn n ba ri, lati maa fi panu, lati ma fi ṣe oriṣiriṣi, ẹgbẹ tawọn ki i ṣe eyi to n jale tabi ko owo ijọba.
Awọn le ma le nawo to awọn to ku amọ awọn eeyan nigbagbọ nitori awọn to n jade ni NDC, wọn jẹ awọn eeyan to kun oju oṣuwọn, ti wọn nigbẹkẹle ninu wọn. Ko
si eyi to ba oun lẹru pẹlu awọn oludije ẹgbẹ oṣelu yooku.
George -Taylor ni, "Ṣe ẹ mọ pe Sẹnetọ Salisu lo wa nibẹ bayii, awọn eeyan mọ bo ṣe ṣee, to ba tẹ wọn lọrun, wọn yoo tun dibo fun.
"Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ naa ti ṣe e ri, amọ pe wahala wa, to di pe wọn fẹẹ pee lẹjọ, latigba naa ni wọn ti pada silu oyinbo, ko to di pe wọn tun pada wa dije fun gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ti wọn ko fun wọn ni tikẹẹti.
"Ti wọn si wa si PDP, ti a si gbọ pe wọn fẹẹ lọ fun sẹnetọ, ṣugbọn awọn eeyan ni lati roo pe lakooko to wa nipo sẹnetọ tẹlẹ, ṣe o ṣe bo ṣe yẹ.
"Gẹgẹ bi mo ṣe sọ, ibo ọtẹ yii fọwọ ara ẹ ṣe ara ẹ ni, to ba tẹ ẹ lọrun, ti o ba tẹ ọ lọrun, tete wa ki a tun nnkan ṣe".
No comments:
Post a Comment