George-Taylor gba awọn ọdọ nimọran lati kopa to jọju nidii oṣelu - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday, 30 June 2026

George-Taylor gba awọn ọdọ nimọran lati kopa to jọju nidii oṣelu

Oludije fun ipo aṣofin agba niluu Abula fun ẹkun Ogun Central labẹ ẹgbẹ oṣelu NDC, Ọnarebu Rotimi George Taylor ti gba awọn ọdọ nimọran lati rii pe wọn kopa to jọju nidii oṣelu, ki wọn ma ṣe jẹ ki wọn maa jẹ wọn mọ aye.

O sọrọ naa lakooko to n kopa nibi eto ori redio kan Oju koju ni Wise FM. O sọ pe eyi ṣe pataki nitori ọjọ iwaju oṣelu orileede yii.

O sọ pe awọn ọdọ yi nipa pataki lati ko paapaa julọ kuro ninu igbekun gbese nla ti wọn ko wa si.

O fikun ọrọ ẹ pe awọn ọdọ ko gbọdọ maa dibo lasan bẹẹ ni wọn ni lati maa di awọn ipo pataki mu nidii oṣelu.

Oludije aṣofin ọhun tun ṣalaye siwaju pe, " Loju temi, ọdọ ko ṣe e rọ sẹyin ninu eto oṣelu orileede  yii, nitori awọn gan an ni ọjọ iwaju orileede yii. Awọn gbese taa ti jẹ ni wọn yoo rii pe wọn san.

Bẹẹ lo tun fi ẹdun ọkan ẹ han si bi ipọnju, oṣi, baba iṣalẹ nidii oṣelu ati gbigba owo ki wọn to dibo, o ni o buru ju, o si yẹ ki wọn fopin si.

O iṣoro owo yii ni ko jẹ kawọn to kun oju oṣuwọn raaye dibo wọle. Nitori gbogbo ẹ ni wọn ti fi oṣelu sọ ọ di owo ti ko si yẹ ko ri bẹẹ.

George Taylor sọ pe oloṣelu ti ko ba le fi ọrọ ilu tabi owo ilu to n gba mu idagbasoke wa, oun gan an da kun ipọnju oun oṣi fun araalu.

Lori awọn ti wọn lọ lati inu ẹgbẹ kan bọ si omii, oludije naa kilọ fun oludije to ba ṣẹ bẹẹ lẹyin ibo alabẹsekele kan fẹẹ lu ofin ni, yoo si jẹyan ẹ niṣu pẹlu.

O wa sọ ọ pẹlu Igboya pe oludije wọn fun ipo aarẹ, Peter Obi nikan ni oun gba ti yoo mu atubọtan ba orileede yii.

O gba gbogbo awọn ọmọ orileede yii nimọran lati le ṣatilẹyin fun Peter Obi, ki wọn si fi ibo wọn gbe e wọle.

No comments:

Post a Comment

Pages