Digbi lẹgbẹ oṣelu NNPP Ogun wa fun ibo ọdun 2027- Adele Alaga - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday, 1 June 2026

Digbi lẹgbẹ oṣelu NNPP Ogun wa fun ibo ọdun 2027- Adele Alaga


Adele alaga fẹgbẹ oṣelu New Nigeria People Party, NNPP, nipinlẹ Ọgun, Alhaja Shakirat Idris Arowolo, ti mu da awọn ọmọ ẹgbẹ naa loju pe digbi lawọn wa ninu eto ibo ọdun 2027, pẹlu ireti pe gbogbo awọn oludije wọn ni yoo jawe olubori.

Obinrin naa sọrọ yii nibi ibo abẹle ẹgbẹ ọhun to waye niluu Abẹokuta, nibi ti wọn ti mu Ọnarebu Olubunmi Ẹniọla Adekọya, gẹgẹ bi oludije wọn fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu NNPP.

O sọ pe gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe mọ NNPP ipinlẹ Ogun, ti kọja eyi ti wọn le foju bintin, nitori awọn ipa ti wọn ti ko sẹyin, ti wọn si n tẹsiwaju titi di akoko yii.

Idi niyii tawọn ṣe farabalẹ mu awọn oludije ti wọn koju oṣuwọn fawọn ipo ninu ibo ọdun 2027, tawọn si mọ pẹlu igbagbọ pe wọn yoo gbajọba lọwọ APC.

Arowolo tun ṣalaye siwaju pe awọn kan le maa pariwo kaakiri, ṣugbọn ariwo ọja lasan ni, nitori oludije wọn ti ṣetan lati ta kangbọn pẹlu awọn yooku ti wọn jọ jade dupo.

Lara awọn oludije yooku ti wọn tun mu lati ṣoju ẹgbẹ wọn ni Ọnarebu Olowu Ọlayẹmi Kẹhinde, ti wọn fun ni tikẹẹti lati dije fun ipo sẹnetọ fun ẹkun Ogun East.

Onarebu Taofik  Adisa Adegboyega fun ẹkun Ogun Centre ati Ọnarebu Adeleke Saheed, toun naa dije fun ipo ṣẹnetọ fun Ogun West.

Ọnarebu  Oluwaṣẹgun Rasaq Ṣhofowora ni wọn fun ni tikẹẹti aṣoju-ṣofin fun ẹkun agbegbe Ṣagamu.

Alaga ẹgbẹ naa wa ki awọn oludije wọn yii ku oriire tikẹẹti ti wọn gba naa bẹẹ lo rọ wọn lati ma ṣe rẹwẹsi ọkan rara nitori oun mọ pe gbogbo araalu lo n ṣe ti ẹgbẹ ọhun.

Bakan naa lo rọ ọmọ ẹgbẹ lapapọ lati jumọ wa ni iṣọkan ati irẹpọ ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu awọn oludije wọn pẹlu adura pe wọn yoo ṣe aṣeyọri .

Ninu ọrọ oludije Gomina wọn, Olubunmi Ẹniọla Adekọya, lo ti fi ẹmi imoore ẹ han lori bi wọn ṣe fun ni tikẹẹti lati ṣoju wọn.

O wa ṣeleri fun wọn pe oun ko nii doju ti wọn ati pe oun ṣetan lati ṣaaju wọn wọ Oke-Mọsan lọdun to n bọ.

O bẹbẹ fun ifọwọsowọpọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ fun atilẹyin wọn nitori oun nikan ko lee da ṣe.

Bakan naa ni gbogbo awọn oludije yooku to sọrọ lọjọ naa ṣeleri pe o da wọn loju pe wọn yoo wọle pẹlu atilẹyin Ọlọrun atawọn araalu.

No comments:

Post a Comment

Pages