Ninu atẹjade kan to fi sita lo ti ṣapejuwe ayajọ ọjọ naa gẹgẹ bi eyi to ṣe pataki to si wa gẹgẹ bi iranti ohun manigbagbe.
O ni fun iranti ayajọ ọjọ naa lọdun 1993,ni gbogbo awọn ọmọ orileede yii jade ti wọn si dibo wọọrọwọ fun Oloogbe MKO Abiọla, ṣugbọn tawọn ologun igba naa wọgile, ni eyi to bi araalu ninu ti wọn si ṣe iwọde ọlọkanọjọkan.
Ṣugbọn lọdun 1999,ni a bọ lọwọ ijọba oloogun igba naa tijọba tiwa-n-tiwa si bẹr ni pẹrẹu, eyi to ti le ni ọdun mẹtalelogun bayii..
O sọ pe, "Iwoye temi ni pe lati ọdun mẹtalelogun taa ti bẹrẹ dẹmọkireesi lorileede yii, n jẹ awọn mudunmudun ẹ tẹ wa lọwọ? Njẹ o tiẹ yẹ ki a maa ṣajọyọ ẹ pẹlu akoko taa wa yii".
Alaga YPP tun tẹsiwaju ninu ọrọ ẹ pe ẹdun ọkan lo jẹ pe ọpọ awọn ọmọ orileede yii ni wọn wa ninu inira ati jẹun,pẹlu bi ọrọ aje ṣr n fi ojoojumọ dẹnukọlẹ.
ojoojumọ lo ni ounje gbowo lori, tipatipa lawọn eeyan fi ri ounjẹ jẹ, Iṣoro lawọn obi ṣe n fi tipatipa ran ọmọ wọn iọ ileewe bẹẹ ni itọju ilera naa ko ṣe sọ.
Adeyẹmi tun ṣalaye pe kaka ki iṣoro airiṣẹṣe dinku, ṣe lo tun peleke si, ko ṣiṣẹ fawọn ọdọ niluu.
O ni,"Eyi to tun wa peleke si lakooko yii ni bi eto aabo ṣe dẹnukọlẹ,ariwo ajinigbe ti gbilẹ kaakiri orileede, ko si ifọkanbalẹ fawọn araalu, ipakupa lawọn afẹmiṣofo pawọn eeyan, ijọba tiwa-n-tiwa wa n di nnkan mii-ii.
" Bi wọn ṣe n ji awọn ọmọleewe atawọn agbẹ gbe lakooko yii buru jai, bẹẹ nas ni ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu, iwa ibajẹ ti wa pọ lapọju'
Adeyẹmi sọ pe bi a ṣe n ṣe ayajọ dẹmokireesi lonii, o rọ ijọba apapọ ati tipinlẹ lati gbe igbesẹ lori awọn Iṣoro to n dojukọ awon ọmọ orileede yii, ti ko jẹ ki wọn jẹ mudunmudun ijọba tiwa-n-tiwa to n bẹ lode yii.
O sọ pe aba lori ọrọ ọlọpaa ibilẹ ti wọn ti jirooro le lori, ki awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin lapapọ fọwọ sii, ko si di mimulo lati akoko yii lọ.
O ni ara ọkan ti yoo fopin si idojukọ eto aabo lorileede yii ti ijinigbe ati ifẹmisofo yoo si dinku lawujọ wa.
Bẹẹ lo tun rọ wọn lati ṣiṣẹ lori awọn imayedẹrun wa bii ọna, ọgbin, ipese iṣẹ fawọn ọdọ atawọn nnkan mii, ki wọn si rii pe ọrọ aje wa pada bọ sipo.
O waa ni ẹgbẹ YPP lorileede yii ati nipinlẹ Ogun ti ṣetan lati wa ọna abayp sawọn idojukọ yii bi wọn ba le dibo yan awọn oludije wọn ninu ibo ọdun 2027..Pẹlu ileri pe wọn ko nii jawọn nitanmọ
No comments:
Post a Comment