Nibi ipade awọn alẹnulọrọ ẹgbẹ ọhun to waye ni ọfiisi ẹgbẹ naa to waye niluu Abẹokuta, ni wọn ti gbe igbesẹ ọhun.
Nigba to n sọrọ lori obinrin naa, Gomina Dapọ Abiọdun sọ pe Kudirat lo wẹ to ja kainkain ninu gbogbo awọn ti wọn koju oṣuwọn ti wọn fa kalẹ lati Ogun East.
Ninu ọrọ Yayi, oludije Gomina fẹgbẹ oṣelu APC, o ṣapejuwe igbakeji ti wọn ṣẹṣẹ mu yii gẹgẹ bi ẹni toun nigbagbọ ninu ẹ lati jọ ṣiṣẹ pọ.
O sọ pe oun mọ pe Kudirat kun oju oṣuwọn tawọn le jọ ṣiṣẹ pọ fun igbega, itẹsiwaju ati idagbasoke ipinlẹ Ogun.
Lakooko ti alaga ẹgbẹ naa, Oloye Yẹmi Sanusi, n kede Igbakeji oludije Gomina wọn, o sọ pe ki i ṣe pe awọn ṣadeede mu obinrin naa bikose awọn ifikunkukun tawọn ṣe ni ẹlẹkajẹka ẹgbẹ naa kaakiri ni wọn ti fọwọ sii.
Bẹẹ lo ṣapejuwe obinrin naa gẹgẹ bi ẹni to ni iriri ati imọ ati pe gbogbo awọn ipa to ti ko lawujọ fun idagbasoke tun jẹ eyi tawọn fi fọwọ sii fun ipo naa.
No comments:
Post a Comment