Wọn ni alaga APC Ogun fẹẹ wọ ẹwu ẹtẹ lori bo ṣe fẹẹ fọmọ ẹ jẹ gaaba ni Ọdẹda fun ipo ọmọ ile igbimọ aṣofin. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 13 May 2026

Wọn ni alaga APC Ogun fẹẹ wọ ẹwu ẹtẹ lori bo ṣe fẹẹ fọmọ ẹ jẹ gaaba ni Ọdẹda fun ipo ọmọ ile igbimọ aṣofin.

Wahala kekere kọ lo n waye nijọba ibilẹ  Ọdda, nipinlẹ Ogun, lori bi wọn ṣe fẹsun kan alaga fẹgbẹ oṣelu APC, nipinlẹ Ogun, APC, Oloye Yẹmi Ṣanusi, lori bi wọn lo ṣe fẹẹ fi tipatipa fa ọmọ rẹ le wọn lori fun ipo ọmọ ile igbimọ aṣofin.

Gẹgẹ bi atẹjade tawọn kan fi sita, wọn sọ pe alaga naa ko le jẹ adari ere bọọlu, ko tun wa sọ ara ẹ di agbabọọlu,nitori idi eyi ko yẹra fun nnkan to n waye lori oludije ọmọ ile igbimọ aṣofin lati Ọdẹda .

Awọn tọrọ naa kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC, lati Ọdẹda sọ pe awọn ko nigbagbọ  ninu ibo ọmọ ile igbimọ aṣofin ti agbegbe naa to ba jẹ pẹ Oloye Yẹmi Ṣanusi ba dari ẹ, nitori awọn ti mọ pe idi ọmọ ẹ toun naa dije ni yoo fẹẹ roko sii.

Wọn sọ pe bi ẹgbẹ oṣelu APC ba fẹẹ ṣeto ibo pamari ti yoo mu alaaia da ni lagbegbe wọn, ki wọn kọkọ yọwọ Yẹmi Sanusi kuro nibẹ nitori ki magomago ba maa waye.

Awọn tọrọ naa kan tun sọ pe ṣe Oloye Ṣanusi nikan ni wọn da aye fun ni ni Ọdẹda pẹlu ipo toun atawọn ẹbi ẹ ti gba lọwọ Gomina Dapọ Abiọdun ati Sẹnetọ Ọlamilekan Yay, ti wọn ni iyẹn ko to, to tun wa ni ki ọmọ ẹ jade dupo ọmọ ile igbimọ aṣofin.

Wọn ohun to n mu ibẹru bojo bawọn ọmọ ẹgbẹ ni bo ṣe kọ ti ko fipo silẹ nitori ọla baba ẹ ti wọn lo si tabuku oṣelu ijọba tiwa-n-tiwa orileede yii.

Wọn wa kesi awọn oloye ẹgbẹ oṣelu APC lapapọ atawọn agba ẹgbẹ nipinlẹ Ogun, lati tete ba wọn sọ ewe alaga ẹgbẹ naa lapapọ mọ agbejẹ lọwọ, ko le jẹ ki alaafia jọba 

No comments:

Post a Comment

Pages