Nibi ipade oniroyin ti ẹgbẹ naa ṣe lo ti sọrọ yii, O sọ pe awọn gbe igbesẹ naa lati fi ṣi ilẹkun silẹ fun gbogbo ọmọ bibi ipinlẹ naa, nitori ẹgbẹ naa jẹ ti araalu,ati pe awọn si wa pẹlu ifarajin wọn lati gba ipinlẹ Ogun lọwọ ifọwọ ọla gba ni nidii oṣelu.
Alaga ọhun tun ṣalaye siwaju pe ipa awọn eeyan pataki ti wọn jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ogun, bii Oloogbe Moshood Kaṣimawo Abiọla, Ernest Ṣonẹkan, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka atawọn mii ko gbọdọ parun fawọn ipo aṣiwaju rere ti wọn fi le lẹ.
O sọ pe,"Ẹgbẹ wa, APM , taa jẹ ẹgbẹ onipaki ti panupọ, a si ti fimọ sọkan pe ẹnikẹni to wa nile igbimọ aṣofin agba, aṣoju ṣofin ati ọmọ ile igbimọ aṣofin, atawọn to ti wa nibẹ tẹlẹ, ti wọn ba fẹẹ jade, ẹgbẹ APM ṣetan lati fun wọn ni tikẹẹti taara gẹgẹ bi oludije"
Sanyaolu to tun jẹ alaga fẹgbẹ oṣelu alapapọ nipinlẹ Ogun, iyẹn IPAC, tun fikun un pe ferese tun si silẹ fun oludije to kun oju oṣuwọn, lati darapọ mọ wọn pẹlu ileri pe wọn ko nii kabamọ, nitori ẹgbẹ wọn ti gbaradi fun ibo to n bọ naa.
O sọ pẹlu igboya pẹlu awọn igbesẹ tawọn gbe yii o da oun loju pe ami rere ni yoo mu wa fawọn oloṣelu lati le jẹ ki wọn mọ pe ọna abayọ rere ni APM jẹ.
Bẹẹ ni Sanyaolu wa gboriyin fun alaga ẹgbẹ naa lapapọ, Yusuf Dantalle, fawọn ipa to ti ko fun imugbooro ẹgbẹ naa.
Wọn tun fi idunnu wọn han fun aṣeyọri nla ti wọn ṣe laipẹ yii nipa bi ẹja nla kan, Bala Mohammed atawọn eeyan ṣe fi PDP silẹ bọ si APM.Sanyaolu ni oriire nla ni.
No comments:
Post a Comment