Oludije ọhun to wa lati ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, lo ti sọ pẹlu igboya pe oun ti ṣetan lati dari ipinlẹ Ogun, ki awọn ohun idagbasoke le tubọ tẹsiwaju.
Lakooko to ṣabẹwo lọọ sọdọ awọn eeyan ẹ ni Ọlawale to jẹ oniṣowo nla, ati olookowo, to ti ni iriri lati bi ọdun mẹẹẹdọgbọn sẹyin ninu idagbasoke ọrọ aje ti sọ pe jijade dupo gomina oun lati lo ọgbọn ti Ọlọrun ọba fun oun lati fi wa ọkọ ipinlẹ Ogun si ebute ire.
Pasitọ Ọlawale tun fikun ọrọ ẹ pe ti oun ba le di gomina oun yoo rii pe wọn da awọn ileeṣẹ nla, to yatọ sawọn eyi to ti wa nilẹ nipaṣẹ awọn ipa toun naa ti ko nipa ọrọ aje.
O ṣalaye siwaju pe bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn to ti dari ipinlẹ naa lo sa ipa wọn lori imayedẹrun ati idagbasoke fawọn araalu ṣugbọn akiyesi oun ni pe ọpọ nnkan bayii ni ko de igberiko lati jẹ anfaani, eyi toun yoo mu ni ọkunkundun.
Bẹẹ lo sọ pe lara erongba oun ni ki iṣẹ dinku lawujọ, ki iṣẹ wa fawọn ti ko niṣẹ.O sọ pẹlu ipinnu pe lṣẹ yoo pọ janturu, ti ironilagbara yoo si pẹlu nipaṣẹ awọn olokoowo to ba wa daṣẹ silẹ.
Ọlawale waa sọ pe ki i ṣe pe oun ṣadeede jade bi ko ṣe pe oun gba itọsọna lati ọdọ Ọlọrun.
Nigba to n dahun si ibeere awọn eeyan lọjọ naa lo ti fi wọn lọkan balẹ pe ko si ewu loko, a fi giri aparo ati pe o da oun loju pe gbogbo ogo ẹgbẹ naa to ti lọ ni Ọlọrun yoo da pada lakooko toun.
O wa rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lati wa nisọkan ki wọn si ṣatilẹyin fun ayipada iṣejọba rere ti Ọlọrun fẹẹ ti ọwọ oun gbe kalẹ yii.
No comments:
Post a Comment