Oloye Ademọla Fọlarin fọrọ iwuri ṣapọnle Fasoranti fayẹyẹ ọgọrun-un ọdun lori eepẹ. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday, 11 May 2026

Oloye Ademọla Fọlarin fọrọ iwuri ṣapọnle Fasoranti fayẹyẹ ọgọrun-un ọdun lori eepẹ.

Oloye Ademọla Fọlarin, Agbaakin Mayegun ilẹ Ibadan, to tun jẹ akọwe agba ẹgbẹ Afẹnifẹre, ti ṣapejuwe olori wọn, Oloye Reuben Famuyide Fasoranti, gẹgẹ bi aṣiwaju rere to ti kopa to yanranti, ni eyi ti ko ṣe e gbagbe.

Ninu atẹjade ti akọwe agba ọhun fi sita eyi to fi gboriyin ati iwuri fun olori ẹgbẹ ọhun fayẹyẹ ọgọrun-un ọdun to pe lori ilẹ alaaye lo ti ṣapejuwe ẹ gẹgẹ bi olori tawọn ri ẹkọ gidi kọ lara ẹ.

O sọ pe ni nnkan bi ọdun mejilelaadọta sẹyin loun ti mọ Oloye Fasoranti, nileewe kan ti wọn pe Christ School, ni Ado Ekiti, nibi ti wọn gbe e wa gẹgẹ bi ọga ileewe.

Fọlarin sọ pe lakooko naa oun si jẹ akẹẹkọ, toun wa ni ipele ati pari ẹkọ, nibẹ loun ti kọkọ mọ Aṣaaju Afẹnifẹre yii bii olododo ati ẹni ti ko wọpọ ninu ibawi.

O ni latigba naa fun bi ọdun mọkanlelogoji, lawọn ko tun fi rira, ko to di ọdun 2015, tawọn tun pade, nigba naa o ti di olori Afẹnifẹre.

Fọlarin ṣalaye siwaju sii pe, " Bi mo tun ṣe pade wọn lẹẹkeji lọdun 2015, ẹ ma jẹ ko ya yin lẹnu pe gbogbo ero mi akọkọ lori wọn ko yipada fun iwa rere ti Ọlọrun fi jinki wọn."

Bẹẹ lo tun ṣapejuwe Fasoranti bi ẹni ti kii ṣe ojuṣaaju nidii oṣelu, tabi oju aye paapaa julọ lakooko to ba ara ẹ nibẹ ọpọlọ pipe to ni Ọlọrun fun un tubọ muu ṣe awọn aṣeyọri ti ko lẹgbẹ.

Akọwe agba naa tun tẹsiwaju pe paapaa julọ gẹgẹ bi olukọ,Fasoranti jẹ ẹni to n gba alaafia laaye koda nidii oṣelu.O ni ko sẹni to ba a nibi abosi tabi ibi ti wahala ba ti fẹẹ waye.

O ni ṣe ni wọn maa n farabalẹ daadaa lati mọ ibi ti nnkan n lọ ati ọna abayọri to tọ ọ si.

Fọlarin tun sọ pe, " Latigba ti mo ti mọ Baba Fasoranti, mi o ri ki wọn binu tabi fi huwasi, wọn ni ẹmi idariji.

Mo ranti lọdun 2023, nigba ta a pnnu pe ki a ṣatilẹyin fun Aṣiwaju Bọla Ahmed lati di aarẹ, ko fi ọrọ naa falẹ to fi gba a wọle, to ni a gbọdọ rii pe a ṣe aṣeyọri lee lori."

Ọdun 1952,  lo ni baba naa ti n ṣe aṣiwaju ninu awọn ẹgbẹ onitẹsiwaju, o si wa lara awọn akẹgbẹ ẹ ti wọn jọ wa ninu Afẹnifẹre ti lepa ki atunṣe de ba orileede yii.

 O waa pari ọrọ ẹ pe pẹlu bi Fasoranti ṣe pe ọgọrun-un ọdun bẹẹ ni wọn fẹran lati jẹ ki Yoruba maa gbe ni ifẹ, irẹpọ ati iṣọkan.

O gbadura ki Ọlọrun tunbọ lọra ẹmi baba, Fasoranti, ki wọn pẹ lẹmi ati alaafia.

No comments:

Post a Comment

Pages