Olori ile igbimọ aṣofin Ogun fẹmi imoore han si Abiọdun, Ọṣọba, Yayi atawọn agba ẹgbẹ ni Ọdẹda. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 15 May 2026

Olori ile igbimọ aṣofin Ogun fẹmi imoore han si Abiọdun, Ọṣọba, Yayi atawọn agba ẹgbẹ ni Ọdẹda.

Yoruba bọ wọn ni bi a ba ṣe ni loore ọpẹ ni a n dun, eyi lo mu ki olori ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun, Oludaisi Oluṣẹgun Ẹlẹmide, ṣe fi ẹmi imoore han lori bi wọn ṣe muu iyen kọnsẹnsọ, lati dije fun ile igbimọ aṣofin lati agbegbe Ọdẹda labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ lanaa, ni wọn yanju awuyewuye to n ṣele lori ipo ọmọ ile igbimọ aṣofin lati Ọdẹda laaarin Ọnarebu Oluṣẹgun Ẹlẹmide ati Adebayọ Ọlayẹmi Sanusi, to jẹ ọmọ alaga fẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun iyẹn Oloye Yẹmi Ṣanusi.

 Ipade ti wọn ṣe yii pẹlu awọn agba ẹgbẹ oṣelu lati Ọdẹda, ti wọn ni Gomina Dapọ Abiọdun ati Senẹtọ Ọlamilekan Adeọla atawọn mii-ii naa wa nijokoo ni wọn ti fẹnu ko lati mu Ẹlẹmide ni tikẹẹti oludije lati agbegbe naa.

Loju ẹsẹ tiroyin ọhun fi gba igbooro ni inu awọn alatilẹyin Ẹlẹmide ti n dun ti wọn si n si ọpẹ fun Ọlọrun, nitori Irinajo ti wọn ti rin lori ọrọ naa ki i ṣe keremi gẹgẹ bi a ti gbọ.

Ni aarọ yii naa ni olori ile igbimọ aṣofin ọhun waa fi ẹmi imoore ẹ han si Gomina Dapọ Abiọdun, Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba, Sẹnetọ Ọlamilekan Adeọla, Yayi atawọn agba ẹgbẹ lati Ọdẹda lori bi wọn ṣe ri ọrọ naa yanju nitubi-inubi.

O sọ pe, "Lonii, mo da gbogbo ogo ati ọla pada si Ọlọrun ọba, fun oore ọfẹ ati aanu rẹ tun sọrọ ninu aye wa, niwọngba ti Ọlọrun ti fọwọ si irinajo yii, ko si ẹni to lee da duro.

O tẹsiwaju pe oun dupẹ lọwọ Gomina Abiọdun fun atilẹyin ẹ gẹgẹ bi baba ati ọgbọn ti Ọlọrun fun un lati le jẹ ki alaafia tubọ maa jọba nipinlẹ Ogun.

Bẹẹ lo tun dupẹ lọwọ Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba fawọn igbesẹ aṣeyọri ti wọn gbe fawọn ilanilọyẹ wọn.

Bakan naa lo tun dupẹ lọwọ Senetọ Ọlamilekan Yayi fawọn ipo aṣaaju to fi jẹ ki ọrọ naa yanju si ibi ti wọn n fẹ.

O wa ki awọn agba ẹgbẹ APC ni Ọdẹda fawọn atilẹyin wọn. O ni ifarajin wọn tun jẹ ọkan gboogi ti ko ṣe gbagbe.

Ẹlẹmide sọ pe bi wọn ṣe mu oun fun oludije yii ki i aṣeyọri toun nikan, bi ko ṣe fun isọkan, itẹsiwaju ati ilọsiwaju fun gbogbo eeyan lati le jẹ ki idagbasoke tunbọ wa.

O ṣeleri pe oun yoo tẹsiwaju ninu iṣẹ iṣin awọn araalu pẹlu ifarajin ati ifarasin, laini doju ti wọn rara.

No comments:

Post a Comment

Pages