Mama iyawo Tunde Lẹmọ jade laye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday, 18 May 2026

Mama iyawo Tunde Lẹmọ jade laye

Wọn ti kede iku ọkan lara Mama ti wọn farajin fun Ọlọrun ko to di pe wọn jade laye, Dikinnẹsi Racheal Adediran Coker, to jẹ Mama iyawo igbakeji ọga agba banki ilẹ wa tẹlẹ iyẹn Oloye Tunde Lẹmọ.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ, ọdun mẹrinlelaadọrun ni Mama naa lo laye, ko to jẹ ipe Ọlọrun.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹrin, ọdun 1924, ni wọn bi Raceal ni Aṣigidi, niluu Ijẹbu Igbo si aarin Alagba Abel Adekanu Oṣoyade ati Emily Adebọwale Oṣoyade ti wọn jẹ obi ẹ. Ipo kẹta lo si wa ninu awọn ọmọ mẹrin ti wọn bi.

Ijẹbu Igbo yii naa lo ti lọ sileewe alakọọbẹrẹ ni St Stephen Aṣigidi nigba to si pari ẹkọ ẹ aye ojọun iyẹn Standard 6 nileewe St John, Oke Agbo ni
 1948.

Ọdun 1949 lo di araalu Eko lati bẹrẹ igbesi aye tuntun, ko si pẹ lo bẹrẹ iṣẹ ni J A Ajayi Brothers, lẹyin igba diẹ to ti n wa iṣẹ.

Ifẹ to ni si iṣẹ akọwe, lo muu lọọ forukọsilẹ nileeṣẹ tẹwetẹwe ni Oluṣọla Commercial Typing Bureau nibẹ lo si ṣe alabapade ọkọ ẹ, Obadiah Olutosin Oluṣọla Coker.

Lẹyin igbeyawo wọn ni Mama Racheal da ileewe silẹ, tileewe naa si gbooro di nla.

Gẹgẹ bi onigbagbọ ododo ọdun 1968  lo fi igbe aye ẹ silẹ fun Kristi ninu ijọ CAC, to si ṣe iribọmi lọdun 1969, nibi to ti gba ẹmi mimọ.

Ọdun 1990 si 1992, ni a gbọ pe o lọọ sileewe ẹkọ Bibeli ti wọn si ta ami ororo lee lori gẹgẹ bi Diakoni obinrin lọdun 1999.

Ọpọ ipo ni Racheal di mu ninu ijọ Ọlọrun nibi ti wọn ti fara sin fun Ọlọrun ti wọn si kede ọrọ Ọlọrun ko to pe akoko to ti wọn ni ki wọn wa ji ihin iṣẹ irinju wọn.

Ọmọ marun un, ọmọ ọmọ ati ọmọ ọmọ ọmọ ni iya naa fi saye lọ.

Ọjọbọ Tọsidee, ọjọ kejidinlọgbpn ni ayẹyẹ aisun onigbagbọ yoo waye nigba ti wọn yoo sinku lọjọ keji ẹ.

No comments:

Post a Comment

Pages