Ẹnu o gba iroyin lọsẹ to kọja niluu Abẹokuta nigba ti igbakeji ọga agba banki ilẹ wa, Oloye Tunde Lẹmọ, ṣoku ana ẹ, iyẹn Dikinẹẹsi Racheal Adediran Coker (Ọṣọyade) to jẹ mama fun Pasitọ Oluyẹmi Lẹmọ.
Ayẹyẹ ọhun to waye lawọn ọtọkulu ilu jakejado ti wa lati wa ṣẹyẹ ikẹyin fun iya agba ọhun to jade laye lọjọ laye ninu oṣu kẹta, ọdun yii lẹni ọdun mẹrinlelaadọrun.
Isin asalẹ onigbagbọ ni wọn fi kọkọ bẹrẹ to waye ni gbọngan Henry Townsend, ni ṣọọṣi St Peters Cathedral, Ake.Nigba ti isin isinku ati idupẹ waye ni ṣọọṣi Christ Anglican,Iporo Ake, niluu Abẹokuta.
Lara awọn eeyan pataki to wa nibẹ lọjọ naa ni Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, Sẹnetọ Gbenga Ọbadara, Ọtunba Tunji Akinlade, Ọba Edu Ifayọmi atawọn eeyan pataki mii-ii, to fi mọ awọn ẹbi,ọrẹ ati ojulumọ.
Nigba ti wọn ṣapejuwe mama naa nigba to wa laye, gbogbo awọn to sọrọ ni wọn sọ pe akinkanju, olujọsin to tun farajin ni wọn, ti wọn si ko ẹbi mọra ati pe wọn kii fẹẹ kiya jẹ ẹni to ba wa lẹgbẹ wọn.
Gbajumọ olorin nni, Taiwo Akinwale Oguntade tọpọ awọn eeyan mọ si Big Tee lo fere da awọn eeyan lara ya lakooko wẹjẹ-wẹmu.
Gbogbo ọna ni Oloye Tunde Lẹmọ ati iyawo ẹ, gba lati rii pe ayẹyẹ oku mama naa dun, o si larinrin, tawọn alejo ti wọn wa naa si gbadun ara wọn pẹlu.
No comments:
Post a Comment