Johnson Akinpelu
Ọpọ awọn araalu lọrọ naa n ṣe ni kayeefi pe ki nnkan to n ṣẹlẹ, ṣe ọkunrin naa ko fẹẹ ṣe oṣelu mọ ni tawọn kan si sọ pe o ṣee ṣe ko fẹẹ kọjumọ okoowo ẹ ni.
Ṣugbọn lojiji ni iroyin gba igbooro pe Ajadi ikọ gẹgẹ bawọn eeyaan ẹ ṣe maa n pe ti tẹsiwaju nidii oṣelu, o si ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP, ipinlẹ Ọyọ.
Bi a ba ni ka sọ ti ododo, irinajo naa ko rọrun lati fi ẹgbẹ kan silẹ bọ si ẹlẹkeeji, ko si waa di oṣupa to n tan ka kaakiri aye ninu ẹgbẹ ọhun.
Ibeere tawọn eeyan tun beere ni pe ipo wo gan-an lo fẹẹ jade fun, ọrọ yii ni wọn si n fa lọwọ ti Ambasedọ Ajadi fi sọ pe ipo gomina loun fẹẹ jade fun ati pe oun ni omi tuntun kẹta ti wọn n reti.
Gbogbo wa la si mọ pe Gomina Ṣeyi Makinde, to wa nipo bayii lawọn araalu mọ si Omituntun kin in ni ati keji nitori awọn iṣẹ akanṣe to ti ṣe, ni eyi to ti mu idẹrun ba araalu.
Ohun pataki ti wọn lo jẹ Ajadi logun ni lati tẹsiwaju awọn ipa ribiribi ti Makinde fi silẹ, nitori o gba a gẹgẹ bi awikọṣe gomina to nifẹẹ awọn eeyan ẹ denu.
Nibi ti Ajadi de, ko jẹ ki oṣelu de ko to maa ran awọn araalu lọwọ, ko si da apa kan si, fi apa kan silẹ, gbogbo awọn eeyan ran lọwọ lati mu inu wọn dun.
Bo tilẹ jẹ pe awọn kan sọ pe o ṣe waa jẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ti wahala wa ni ọkunrin yii ti jade dupo pẹlu erongba ẹ lati di gomina.
Ṣugbọn oludije yii ko ri ro nitori igbagbọ to ni pẹlu Gomina Ṣeyi Makinde si duro gbọingbọin bẹẹ lo jẹ ki wọn mọ pe ibi to ba le ni wọn n ba ọmọ ogun.
Lojumọ to si mọ ọn lonii, ko sibi tọwọ iranwọ ẹ ko tan an de, ti wọn si pe e ni ẹni aye n fẹ.
Bawọn onigbagbọ ta a mọ si Kristẹẹni ṣe n fi adura ran an lọwọ bẹẹ lawọn musulumi naa ko gbẹyin, nitori wọn mọ pe bi ọkunrin yii ba di gomina yoo ṣe ju bẹẹ lọ.
Latilẹ ni Ajadi Oguntoyinbo ti fẹran lati maa kopa nipa ọlọrọ ẹsin mọ, ko to akoko yii lo ti maa n ko awọn ẹlẹsin musulumi jọ lakooko awẹ niluu Ibafo, nibi ti ọfiisi ẹ wa.
Bakan naa ni gbogbo ọjọ kin in ni, oṣu kin in ni, ọdun lo maa n dana ariya ọdun silẹ fawọn araalu.
Ọpọ ajọ ni ọkunrin yii ti da silẹ fawọn eeyan nibi to ti n ro wọn lagbara, ọpọ awọn eeyan kan lo si n gbowo oṣu titi di akoko yi.
Bẹẹ ni Ajadi tun mu eto ẹkọ ni pataki, ko to bẹrẹ ipolongo tabi ni lọkan lati ṣe oṣelu lo ti n kopa lati ran awọn ọmọ ileewe lọwọ.
Lọsẹ to kọja yii lo tun fawọn ọmọ ileewe kan niluu Ibadan lawọn ohun elo ẹkọ wọn fun saa ti wọn ṣẹṣẹ wọle yii.
Ko si digba ti a ba sọ ki a to mọ pe Omituntun kẹta ti wọn reti nipinlẹ Ọyọ, nitori idi eyi, ẹyin agba ẹgbẹ oṣelu PDP, ọmọ Ajadi kun oju oṣuwọn lati ṣe gomina bi ẹ ba jẹ ka pa ero pọ.
No comments:
Post a Comment