Ẹṣẹ wo ni ilẹ Ijẹbu ṣẹ Dapọ Abiọdun to fi mu ifasẹyin ba wọn-Sẹnetọ Gbenga Daniel - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday, 12 May 2026

Ẹṣẹ wo ni ilẹ Ijẹbu ṣẹ Dapọ Abiọdun to fi mu ifasẹyin ba wọn-Sẹnetọ Gbenga Daniel

Sẹnetọ Gbenga Daniel, to n ṣoju Ogun East, nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja, ti sọ fawọn ara Ijẹbu pe ki wọn beere lọwọ Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun, pe ẹṣẹ wo ni wọn ṣẹ ẹ to n fi dena awọn ohun rere to yẹ ko wọnu ilu naa.

O sọrọ yii nibi eto ironilagbara to n ṣe lawọn ijọba ibilẹ to wa labẹ Ogun East, eyi to waye ni Ọbalọfin Court, Ijẹbu Ode.

Bakan naa lo sọ pe oun ti ṣetan lati fẹyin Gomina Dapọ Abiọdun gbolẹ nibi ibo pamari ti yoo waye laarin awọn mejeeji fun ipo Sẹnetọ.

O sọ fawọn alatilẹyin ẹ pe ki wọn ma jẹ ki wọn da girigiri bo wọn lọjọ naa ki wọn rii pe wọn jade lawọn wọọdu wọn pẹlu kaadi ọmọ ẹgbẹ.

O sọ pe ibo ọhun to maa waye ni Ogunjọ, oṣu yii, lo ti pe Dapọ Abiọdun ko jade lati jẹ kawọn jọ ta kangbọn lati mọ ẹni tawọn eeyan wa lẹyin ẹ ju.

Sẹnetọ Gbenga Daniel toun naa ti figba kan jẹ gomina nipinlẹ Ogun tun fikun ọrọ ẹ pe o ti yẹ kawọn olugbe Ogun East, ti yẹ ki wọn ma ṣegbelewọn awọn to yẹ ki wọn ṣoju wọn.

O ni ọrọ tẹnu kọ, ohun to da oun loju ni pe bi wọn ba faye gba oun ati Dapọ Abiọdun nibi ibo ọhun, alubolẹ loun yoo na.

Daniel sọ pe lẹyin toun ti gbejọba kalẹ lẹyin ọdun mwjila sẹyin tawọn eeyan ni koun jade dupo aṣofin, iṣẹ toun ti ṣe laarin ọdun mẹta ko ṣe e lafiwe.

Ati pe ironilagbara toun ṣe fawọn araalu, ko ṣẹṣẹ bẹrẹ, ki oun to depo ni Ọlọrun ti lo oun lati maa ṣaanu fawọn eeyan.

O waa ni kawọn ara Ijẹbu beere lọwọ Gomina Dapọ Abiọdun, idi ẹ to fi n fọwọ aago ilẹ Ijẹbu ṣẹyin lori awọn ohun idagbasoke to ti yẹ ki wọn ṣe fun wọn.


No comments:

Post a Comment

Pages