Ẹgbẹ oṣelu YPP Ogun bawọn ọmọde atawọn musulumi ṣajọyọ ọdun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 27 May 2026

Ẹgbẹ oṣelu YPP Ogun bawọn ọmọde atawọn musulumi ṣajọyọ ọdun

Ẹgbẹ oṣelu Young Progressive Party, tipinlẹ Ogun ti ki gbogbo awọn ewe ku ayẹyẹ ayajọ ọdun ọmọde ti wọn ṣe lonii.

Bakan naa ni wọn tun ki gbogbo awọn musulumi ku ayẹyẹ ọdun ileya ti wọn ṣe, eyi to jẹ ayẹyẹ onibeji.

Ninu atẹjade ti alaga ẹgbẹ naa, Ọnarebu Adeyẹmi Oluwaṣeyifunmi fi sita lonii lo ti bawọn yọ pe oju tun ri ọdun mejeeji layọ ati alaafia.

O sọ pe gẹgẹ bi a ṣe mọ pe ogo ọjọ iwaju lawọn ọmọde.Nitori ẹ lo ṣe ni a gbọdọ jẹ ki erongba wọn, etọ ekọ ati aabo wọn jẹ wa logun lorileede yii.

Alaga ọhun tun tẹsiwaju ninu ọrọ ẹ pe, " Bi a ṣe n sọdun fawọn ẹbun ti Ọlọrun fi ta wa lọrẹ lonii, mo rọ ijọba, obi ati alagbatọ lati ma ṣe rẹwẹsi nipa fifi ipinlẹ rere silẹ fawọn ọmọ wa nitori ki wọn le wulo fun awujọ lọjọ iwaju.

"Inu ẹgbẹ oṣelu YPP ko dun lori bawọn ọmọ kan ṣe wa nigbekun awọn ajinigbe lawọn ibi kan lorileede yii. A rọ ijọba apapọ atawọn ẹlẹkajẹka eto abo lati gbe igbesẹ kawọn ọmọ to ninu igbekun ọhun le gba ominira ki wọn le pada sọdọ awọn obi wọn"
     
Adeyẹmi tun fikun ọrọ ẹ pe awọn ọmọde ki i ṣe ẹni ti wọn le ṣe bo ṣe wọn nitori awọn ni iṣura ati idunu ọjọ ọla ati ọjọ iwaju.

O  wa sọ pe, "Bawọn ogo wẹrẹ ṣe n ṣajọyọ ọdun wọn kaakiri orileede yii, a gbadura ki Ọlọrun tubọ fun wọn ni alaafia pipe, ki wọn tubọ maa dagba ninu ẹmi, ninu ẹkọ ati oore ọfẹ ti ko lopin.

Bakan naa ni alaga YPP ipinlẹ Ogun, tun lo anfaani ọdun ileya tawọn musulumi n ṣe gẹgẹ bi ifarajin, sisun mọ Ọlọrun ati ifarada fun Ọlọrun .

O ni o ran wa leti lati wa ifẹ, isọkan,ki a si mu imọtara ẹni nikan kuro, ati pe o n fẹ ki a maa ran ara wa lọwọ paapaa julọ awọn ọmọ ti ko niya.

Adeyẹmi ṣalaye siwaju pe," Gẹgẹ bi a ṣe sọdun ileya lonii, mo gbadura ki Ọlọrun gbọ gbogbo aniyan wa,ko si ṣe itẹwọgba fawọn isin wa. Ki ayọ ati ibukun ayajọ ọdun ileya yii ko ba le ẹbi wa pẹlu alaafia ati ayọ,"

Alaga ọhun wa gba awọn ẹlẹyinju aanu lamọran lati dide iranwọ fawọn to ku diẹ kaato gẹgẹ bi a ṣẹ mọ  pe a n koju ipenija ọrọ aje to dẹnukọlẹ, ti nnkan ko lọ bo ṣe yẹ fun wọn, o ni gẹgẹ bi islam ṣẹ kọ wọn.

Bẹẹ ni ẹgbẹ YPP tun rọ gbogbo ọmọ orileede yii lati wa nisọkan, alaafia ati abo to peye. Bakan naa lo ni a tun gbọdọ maa ṣatilẹyin fun ofin lawọn agbegbe nipa finfinmu finlẹ fawọn oniṣẹ ibi laduugbo wa.

O waa gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki ayajọ ọdun awọn ọmọde ati ileya ọdun yii mu atunṣe rere ba orileede  wa laapọ 

No comments:

Post a Comment

Pages