Ẹgbẹ ADC ipinlẹ Ogun fun Biọdun Ogundipẹ ni tikẹẹti oludije ipo gomina fọdun 2027 - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday, 25 May 2026

Ẹgbẹ ADC ipinlẹ Ogun fun Biọdun Ogundipẹ ni tikẹẹti oludije ipo gomina fọdun 2027

Dokita Biọdun Ogundipẹ, lo jawe olubori gẹgẹ bi oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, nipinlẹ Ogun.

Nibi ibo abẹle ẹgbẹ ọhun to waye niluu Abẹokuta, ni Ogundipẹ ti fẹyin awọn meji yooku ti wọn jọ dije janlẹ.

Nigba to n ka esi ibo abẹle to waye ọhun, Ọgbẹni Adeniyi Adams, to jẹ alaga to ṣeto idibo, sọ pe awọn mẹta ti wọn jọ dije gomina naa ni Dokita Biọdun Ogundipẹ, Ọtunba Jimi Lawal ati Arabinrin Marie Oduṣina.

O sọ pe ibo 9,370 ni Ogundipẹ ni, nigba ti Jimi Lawal ni 6,812 ti Arabinrin Marie Oduṣina ni 2,349.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin to gbegba oroke, Dokita Ogundipẹ fi idunnu ẹ han lori bo ṣe jawe olubori ati bo ṣe ri atilẹyin awọn ọmọ ẹgbẹ.

O sọ pe ibo abẹle ti waye, o si ti lọ, ni bayii akoko ti to fawọn ọmọ ẹgbẹ lati papọ soju kan, lati ri i pe wọn jawe olubori fun ibo gomina.

Oludije gomina ọhun tun sọ siwaju pe  oun rọ gbogbo awọn ti wọn jọ jade dupo lati jọ ṣiṣẹ pọ, ki wọn le gbe ẹgbẹ yii soke lati le mu idagbasoke ba ipinlẹ Ogun. Nitori ẹbi kan naa ni gbogbo wọn.

No comments:

Post a Comment

Pages