O sọrọ yii lakooko to n kede ipinnu ẹ lati jade dupo labẹ aṣia ẹgbẹ onipaki APM, tipinlẹ Ogun, eyi to waye ni ọfiisi ẹgbẹ ọhun lọjọruu, Wẹsidee niluu Abẹokuta.
O sọ pe oun jade lati waa dije ni, to si da oun loju pe oun yoo jawe olubori.
O kọkọ fi ẹmi imoore ẹ han si awọn ọmọ lori bi wọn ṣe pọ yanturu lari wa sibi eto ọhun pèlu ileri pe oun ko nii jawọn nitanmọ.
Babajide fikun ọrọ ẹ pe ko si ibẹru fun ọmọ Ọlọrun toun o ati pe oun ti fi ti Ọlọrun siwaju oun gbogbo.
O ṣalaye siwaju pe " Mo wa lonii lati kede pe mo fẹẹ dije nitori mo nigbagbọ pe mo kun oju oṣuwọn gẹgẹ bii awọn yooku, ti mo si mọ pe iṣejọba mi yoo bẹrẹ lọdun 2027, Mo si ni agbọye daadaa pẹlu awọn eeyan ipinlẹ Ogun, nitori mo gbe pẹlu wọn ju awọ ta a ọ dije mi in lọ."
Bakan naa lo mẹnuba awọn eto to nii lọkan fawọn araalu bi wọn ba le dibo yan an wọle gẹgẹ bi gomina.
Ọkunrin naa sọ pe oun fẹẹ wa sin awọn eeyan oun lọna ti ayipada rere yoo fi de ba gbogbo ọtọkulu ilu
O waa rọ ọmọ ẹgbẹ lati fimọsọkan ki wọn foun ni tikẹẹti gẹgẹ bi oludije wọn pẹlu ileri pe oun ko nii doju ti wọn.
Ninu ọrọ Abayọmi Sanyaolu, to jẹ alaga ẹgbẹ ọhun lo ti fi igbagbp ẹ han si oṣelu igberiko, o ni gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe mọ pe ipinlẹ Ogun ko ṣee fọwọ rọ sẹyin nidii oṣelu.
O ni aye ṣi fun tọmọde tagba lọkunrin ati lobinrin lati darapọ mọ ẹgbẹ APM, ki wọnle jọ ṣiṣẹ pọ gba akoso ijọba lọdun 2027.
No comments:
Post a Comment