APC fa ọwọ Ọtunba Gbenga Daniel soke gẹgẹ bi oludije sẹnetọ Ogun East lẹẹkeji - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday, 12 May 2026

APC fa ọwọ Ọtunba Gbenga Daniel soke gẹgẹ bi oludije sẹnetọ Ogun East lẹẹkeji

Lọjọ Iṣẹgun Tusidee, ana,lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, ti Ogun East, kede Sẹnetọ Gbenga Daniel gẹgẹ bi ẹni ti wọn mu lati dije fun ipo to wa naa lẹkeeji.

Nibi ayẹyẹ ironilagbara ati ijabọ iṣẹ eyi ti Aṣofin Gbenga Daniel ṣe kaakiri Ogun East lati ọdun to kọja ti wọn fi sọrii BATOGD, to waye ni Ọbalọfin Court, Ijẹbu Ode ni wọb ti kede ẹ. 

Ninu ọrọ Akọgun Kọla Ọnadipẹ lakooko to n ṣaaju awọn ikọ ti wọn fa ọwọ Daniel soke, o sọ pe awọn ṣeleyii gẹgẹ bi ilana ati ofin ti ẹgbẹ la kalẹ.

Wọn lawọn fẹẹ ki Ọtunba Daniel tẹsiwaju awọn iṣẹ ẹ to n ṣe, nitori o ṣoju wọn daadaa nile igbimọ aṣofin niluu Abuja .

Bẹẹ lo tun sọ pe awọn fẹẹ jẹ ki Daniel lọọ pari awọn iṣẹ to ṣe ku nipa idagbasoke Ogun East.

Ko tii pari ọrọ ẹ tan ti ariwo fi n lọ kaakiri lati ọdọ awọn eeyan to wa nibẹ pe awọn fọwọ si bẹẹ lawọn ṣetan lati ṣatilẹyin fun un.

Ninu ọrọ Sẹnetọ Gbenga Dainel to ba awọn oniroyin sọ lẹyin ti wọn fa ọwọ ẹ soke lo ti sọ pẹlu igboya pe o da oun loju pe bi oun ati Dapọ Abiọdun ba jọ pade ni ibo pamari, oun yoo fẹyin ẹ gbolẹ gan an ni.

No comments:

Post a Comment

Pages