Alaga YPP nipinlẹ Ogun gboriyin fawọn aṣaaju wọn nilẹ Yoruba fun ipade nla ti wọn ṣe - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 10 May 2026

Alaga YPP nipinlẹ Ogun gboriyin fawọn aṣaaju wọn nilẹ Yoruba fun ipade nla ti wọn ṣe

Ọnarebu Adeyẹmi Solomon Oluwaṣeyifunmi, to jẹ alaga fẹgbẹ oṣelu Young Progressive Party, YPP, nipinlẹ Ogun, ti gboṣuba fawọn aṣaaju ẹgbẹ ọhun lori aṣeyọri ti wọn lori gbigba alejo ipade ti wọn tilẹ Yoruba, eyi to waye niluu Ibadan.

Gẹgẹ bi atẹjade ti ọkunrin naa fi sita lonii lo ti fi idunnu ẹ han. O nibi Ipade ọhun ni wọn ti ṣagbekalẹ oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu naa, iyẹn Ọgbẹni Julius Ọlajide Filani.

Alaga naa ṣalaye pe ipade ọhun to waye lọjọ Furaide to kọja yii lo ṣapejuwe gẹgẹ bi ohun manigbagbe ninu Itan oṣelu ati ijọba tiwa-n-tiwa lorileede yii.

O sọ pe  nibi ipade ọhun tawọn agbaagba oṣelu ẹgbẹ ti peju pesẹ, ti alaga wọn ni ẹkun ilẹ Yoruba, Dokita Oluwole Britto, atawọn oloye ẹgbẹ wọn kaakiri ipinlẹ Yoruba naa ti wa nibẹ pẹlu.

Lara wọn ni: Ọnarebu Adeyẹmi Adedeji, lati Ọyọ,  Ọnarebu Adeyẹmi Solomon Oluwaṣeyifunmi, lati Ogun, Don Ojon, Ondo,  Ariyibi Kafayat Abọlanle, Eko, Enock Ọlalekan,Ọṣun ati Owooọla Daramọla lati Ekiti.

Nibi ipade ọhun ni alaga ẹgbẹ naa nilẹ Yoruba, Britto, ti ki awọn ọmọ ẹgbẹ kaabọ, to si gba wọn lamọran lati duro ti ẹgbẹ naa gbọingbọin, bẹẹ lo si rọ wọn ki wọn gba ifẹ ati isọkan laaye ninu ẹgbẹ YPP.

Alaga ẹgbẹ naa lati Ọyọ, to tun gba wọn lalejo, Ọnarebu Adeyẹmi Adedeji, dupẹ lọwọ awọn akẹgbẹ ẹ fun ẹmi ifarajin ati afojusun ti wọn ti n ni latẹyin wa.

Bẹẹ lawọn aṣaaju mii to tun sọrọ lo gboriyin fun oludije fun ipo aarẹ wọn Ọgbẹni Julius Ọlajide Filani fun ẹmi igbooya to ni lati jade dupo, pẹlu ileri pe awọn yoo ṣatilẹyin nla fun un.

Ninu ọrọ oludije aarẹ fẹgbẹ YPP, Ọgbẹni Filani, oun naa fi ẹmi imoore ẹ han lori ipade to waye ọhun, o waa mẹnuba awọn erongba to ni fun orileede yii to ba depo aarẹ.

Lawọn ẹlẹkajẹka bii eto ọgbin, eto ẹkọ, riro awọn ọdọ lagbar, aabo, idagbasoke ọrọ aje ati imayedẹrun.

O waa lo akoko ọhun lati fi kesi gbogbo awọn ọmọ orileede yii pe ki wọn gbakutu mọ ẹgbẹ oṣelu YPP, kawọn eto ti wọn ni le di mimuṣẹ

No comments:

Post a Comment

Pages