Ninu atẹjade kan to fi sita lo ti sọ pe oun ṣi fikunlukun, toun si n wo bi ilana ẹgbẹ oṣslu APC yoo ṣẹ lọ, nitori naa kawọn oloolufẹ si lọ sinmi ẹdọ.
Sẹnetọ Yayi sọrọ yii lakooko to n fi ilodi ẹ han lori bi wọn ṣe lawọn kan n ṣe patako ati posita ti wọn bẹbẹ fun ko jade dupo.
O kọkọ dupẹ lọwọ wọn fun ifẹ ti wọn ni si oun, amọ ṣa, ki wọn si sinmi gbogbo eleyii, nitori nnkan ni igba ati akoko wa fun.
O ṣalaye siwaju pe akoko ipongo ko tii bẹrẹ ni pẹrẹu.
Yayi sọ pe" Mo gbọ pe awọn kan ti n gbe patako, ti wọn n ṣe posita lati bẹbẹ erongba mi lati dije fun gominɛ, mo dupẹ fun ifẹ tẹ ẹ ni si mi, ṣugbọn mo rọ yin lati ṣe ṣuuru nitori mi o ti fi erongba mi han lati dije, mo jẹ ẹni ṣe ẹgbẹ tọkantọkan lato bi ọdun marundinlogoji ti mo ti wa nibẹ, mo ṣi n ṣe ifikunkukun lọwọ bẹẹ ni mo tun woye ki wọn gbe ilana ẹgbẹ site"
O wa rọ awọn alatilẹyin ẹ ki wọn ifọkansin pẹlu titi gbogbo nnkan yoo fi yọju.
No comments:
Post a Comment