Idi niyii ti ko fi ya wọn lẹnu, bo tilẹ jẹ pe wọn gba kamu nigba ti wọn darukọ Sẹnetọ Solomon Ọlamilekan Adeọla, tọpọ mọ si Yayi, gẹgẹ bi ẹni ti wọn fa kalẹ bi oludije gomina lọdun 2027.
Ipade ẹgbẹ naa to waye ni ọfiisi wọn to wa niluu Abẹokuta, lo fẹẹ jẹ pe ko sawọn gbongbo ti wọn ko si nibẹ.
Lara wọn ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun,awọn gomina ti wọn ti jẹ tẹlẹ bii Arẹmọ Oluṣẹgun Ọṣọba, Sẹnetọ Gbenga Daniel ati Sẹnetọ Ibikunle Amosun, awọn sẹnetọ to ti jẹ atawọn ti wọn wa nibẹ lakooko yii atawọn agbaagba ẹgbẹ.
A gbọ pe lẹyin gbogbo ijiroro wọn ni wọn gba pe o ti to akoko ki ọmọ Yewa naa di gomina, eyi ti wọn ni ko tii ṣẹlẹ ri lati bii aadọta ọdun sẹyin ti wọn ti da ipinlẹ Ogun silẹ.
Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun gan-an lo kede pe lẹyin gbogbo ifikunlukun atawọn ipade ti wọn ti ṣe ni ọlọkan-ọ-jọkan pẹlu awọn ti wọn ti jẹ gomina tẹlẹ atawọn agba ẹgbẹ APC, ki alaafia le jọba pẹlu ifẹ, lawọn ṣe panupọ lati mu ẹnikan ṣoṣo laarin awọn oludije .
Dapọ Abiọdun ṣalaye siwaju pe" Pẹlu ipade ati ifikunlukun taa ṣe papọ, a fimọ sọkan lati mu Sẹnetọ Ọlamilekan Adeọla Yayi gẹgẹ bi oludije wa fun ipo gomina lọdun 2027.
Awọn agba ẹgbẹ ti wọn wa nibẹ ni wọn figbagbọ wọn si Yayi gẹgẹ bi ẹni itẹwọgba lati ọdọ wọn.
No comments:
Post a Comment