Sẹnetọ Iyabọ ọmọ Ọbasanjọ ṣọjọọbi lonii,ni wọn ba rọjo adura lee Iyaniwura lorii, wọn ni ẹlẹyinju aanu ni. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday, 27 April 2026

Sẹnetọ Iyabọ ọmọ Ọbasanjọ ṣọjọọbi lonii,ni wọn ba rọjo adura lee Iyaniwura lorii, wọn ni ẹlẹyinju aanu ni.

Johnson Akinpẹlu

Gẹgẹ bi a ṣe mọ pe pataki ni ọjọọbi jẹ ninu aye ẹda, eyi ti wọn fi maa n dupẹ lọwọ adaniwaye pe o da ẹmi wọn si, ti ọba oke tun fi ọdun kun ọdún wọn lori eepẹ.

Nitori ẹ ni awọn eeyan lagbaaye fi n ba akọni obinrin nni,Aṣofin Iyabọ Ọbasanjọ ṣajọyọ ọjọọbi kọkandinlọgọta to n ṣe lonii.

Bi ọmọ ọlọjọọbi ṣe n forin ọpẹ dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o tun jẹ koun wa laye, toun si wa laaye gẹgẹ bẹẹ lawọn oloolufẹ ẹ naa ko gbẹyin lati ba a kan sara si Ọlọrun

Iyabọ Oluṣọla ọmọ Ọbasanjọ naa ki i ṣeeyan bẹẹ fawọn ipa to ti ko ninu awọn eeyan adarihunrun.

Akinkanju obinrin ti Ọlọrun fun ni ẹmi igboya lati maa fi dari ọpọ eeyan, gbogbo ipo ti di mu lo fi maa ṣe ọmọ araye loore.

Ṣe ti igba to jẹ kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ Ogun ni ẹ fẹẹ sọ ni tabi nigba to di aṣofin fun ẹkun aarin Ogun nile igbimọ aṣofin apapọ niluu  Ẹgba.

Ọbasanjọ ko bawọn lo oṣelu bamubamu ni mo yo, awa o mọ bi ebi n pa ọmọ ẹnikọọkan ati araale ati araata lo n ṣoore fun.

Nitori ẹ ni ajọ Iyaniwura to da a silẹ fi wa titi oni,nipa oṣelu aṣofin ni amọ nipa ti ẹkọ ọjọgbọn tun ni to n kọ wọn lẹkọọ ni yunifasiti.

Adura tawọn eeyan wa n ṣe  fun un ni  ki Ọlọrun tubọ da ẹmi ẹ si, ohun rere gbogbo ki ọba oke tubọ fi ta a lọrẹ, bo ṣe n ṣe ọjọọbi lonii, ki o ṣe ọpọ ẹ lorilẹ.

Aṣofin Iyabọ Ọbasanjọ, igba ọdun kan, ko pẹ, ko gbo lorilẹ alaaye.

No comments:

Post a Comment

Pages