Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi jade tan: O ni mo ṣetan lati dije fun ipo Gomina nipinlẹ Ogun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 17 April 2026

Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi jade tan: O ni mo ṣetan lati dije fun ipo Gomina nipinlẹ Ogun.

 Lati bi oṣu meloo kan lawọn ẹgbẹ oṣelu kan nipinlẹ Ogun, ti n lọọ ṣepade pọ pẹlu oloṣelu nla nni, Ọtunba Ṣẹgun Ṣowumi, lati jade dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu wọn ninu ibo ọdun 2007.

Ṣugbọn ti oludasilẹ ẹgbẹ kan to n wa ọna abayọ iyẹn The Alternative si sọ pe to ba ya oun yoo fi erongba oun han faraye nibi toun lọ.

Ni bayii, Ọtunba Ṣowunmi to tun jẹ Ọdọfin Kemta nilẹ Ẹgba ti waa jade nita gbangba pe oun ṣetan lati dupo gomina lọdun 2027.

O kede yii nibi ipade nla to ṣe pẹlu apapọ ẹgbẹ oṣelu nipinlẹ Ogun, iyẹn IPAC, to waye ni ọfiisi wọn, Ake, niluu Abẹokuta lonii.

Nibi ipade ọhun toju ẹsẹ gbogbo awọn alaga ẹgbẹ oṣelu to wa ninu ẹgbẹ naa ti pe lo ti ṣalaye pe oun ko pada sẹyin mọ rara lati dije fun ipo naa.

Nibẹ lo ti pe awọn alatako oṣelu lati bẹrẹ si nii pilẹ latawọn igberiko  ki wọn papọ lati le dojukọ awọn oloṣelu ti wọn ti ba nnkan jẹ jinna.

O sọ pẹlu igboya oun fẹẹ ki wọn pe oludije gomina ti APC mu lati wa koju oun ninu ariyanjiyan ita gbangba lati fi le mọ ẹni to gbangba sun lọyẹ.

Ṣowunmi tun fikun ọrọ ẹ pe, " Gẹgẹ bi eto idibo oṣelu fọdun 2027, ṣe n wọlẹ wẹrẹ, n jẹ ki a beere lọwọ ara wa,ṣe ipinlẹ Ogun gba lati wuye ni tabi nitori awọn ọmọ wa tabi iran to n bọ, ṣe a maa tẹle ilana rere?"

O ni loootọ ni o ti wa ninu itan pe Ogun West ti wa lara awọn to n jẹ gomina, amọ o ṣekilọ pe irufẹ nnkan bẹẹ ko wa yẹ ko jẹ nipa mimu, eyi to ṣakoba fawọn oludibo lati mu ẹni to ba wu wọn.

Nigba to n kede idupo ẹ, o sọ pe,"Mo fẹẹ jade dupo gomina lọdun 2027, mo rọ yin lati ṣagbekalẹ igbimọ kan dide laarin yin, ti wọn yoo ṣiṣẹ lori bi a ṣe le ṣiṣẹ pọ ti yoo mu imuṣẹ ọhun waye"

Ṣowunmi waa fi aidunnu ẹ han lori ifikunkukun to n waye lori apapọ oṣelu niluu Abuja, o sọ pe igberiko lo yẹ ki iru nnkan bẹẹ ti kọkọ waye.

Bakan naa lo sọ pe oun ko fi gbogbo ara gba ti owo oṣelu, o ni kaka bẹẹ o yẹ ki wọn jọ ṣapero bi eto ipolongo yoo ṣe lọ.

Ko to to akoko yii, ni alaga fẹgbẹ IPAC nipinlẹ Ogun, Abayọmi  Sanyaolu ti mu da Ṣowunmi loju pe awọn gba a gẹgẹ bi oludije wọn

Ati pe bi nnkan ba ṣe n lọ, lawọn yoo jẹ ko gbọ nigba to ya, o waa fi idunnu ẹ han si fun apọnle nla to ṣe sọdọ wọn lati wa kede erongba lati dije fun wọn.

No comments:

Post a Comment

Pages