Ojiṣẹ Ọlọrun naa sọrọ yii lakooko to n waasu nibi ayẹyẹ isin idupẹ ọjọọbi aadọrin ọdun ti Sẹnetọ Gbenga Daniel dele aye, to waye ni ṣọọṣi Abraham Terbanacle, Ṣagamu, nipinlẹ Ogun.
O sọ pe iwa ọmọluabi ti ọlọjọọbi naa hu paapaa nigba to fi jẹ gomina jẹ ere nla lati ọdọ Ọlọrun wa.
Adeboye tun fikun ninu ọrọ ẹ pe ko si nnkan tawọn beere lọwọ ẹ nigba to fi jẹ gomina ti ko nii ṣe fawọn.
O waa gbadura pe ki Ọlọrun tunbọ lọra ẹmi ẹ, ko si fi ẹmi gungun taa lọrẹ.Bẹẹ lo sọ ninu iwaasu ẹ pe gbogbo igba teeyan ba ti n ṣayẹyẹ ọjọọbi, ko maa ranti ọjọ iku naa pe ọjọ kan n bọ ti opin yoo de.
Adeboye loun atawọn ẹbi to fi mọ ijọ ridiimu lawọn ti gbadura fun Gbenga Daniel pe ki Ọlọrun ko jẹ pari irinajo ẹ gẹgẹ bi sẹnetọ Ogun East si rere.
Ninu iṣẹ Aarẹ orileede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, to ran si Ọtunba Gbenga Daniel lo ti kii ku oriire aadọrin ọdun naa.
Bẹẹ lo ṣapejuwe ẹ gẹgẹ bi akọni ẹda to maa n fi gbogbo ara ṣiṣẹ paapaa lakooko to fi jẹ gomina nipinlẹ Ogun. O lawọn ipa to ko ko kere fun idagbasoke ati ilọsiwaju .
Bakan naa ni aarẹ tun mẹnuba awọn iṣẹ akanṣe manigbagbe ti Dainel ṣe, eyi to ni ko ṣee lafiiwe.
O wa gbadura pe ki Ọlọrun tunbọ fun ni ẹmi gungun, alaafia ati ilera to peye ti yoo fi lo aye ẹ.
Nigba toun naa sọrọ loruko Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ẹni ti igbakeji ẹ, Salmọt Oyedele Salakọ ṣoju fun, lo ti ṣapejuwe ọlọjọọbi naa gẹgẹ bii aṣaaju rere to ti fawọn apẹẹrẹ rere to ti wa ni akọsilẹ le lẹ.
Lara awọn eeyan pataki to tun wa nibẹ ni Iyaafin Bọla Ọbasanjọ to ṣoju Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, Sẹnetọ Ibikunle Amosun, Ọba Raṣidi Ladọja,Olubadan tiluu Ibadan, Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Arẹmu Gbadebọ, Ọnarebu Ladi Adebutu atawọn eeyan jakanjakan lawujọ .
No comments:
Post a Comment