Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ipade ọhun ti wọn pe lonii ọjọ Aje, Monde, si gbọngan Adeọla Odutọla, Ijẹbu Ode, ni deede aago mẹwaa aarọ ni wọn sọ di nnkan mii.
Wọn sọ pe bi mọtọ nla alawọ funfun ti Sẹnetọ Gbenga Daniel wa ninu ẹ ṣe n bọ lati wọ ẹnu geeti ipade naa pẹlu awọn eeyan ni wọn ba a gbe ti pa.
Gbogbo arọwa ti wọn pa fawọn to wa lẹnu geeti lati jẹ ki OGD wọle ni ko wọ wọn leti, wọn ni iṣẹ ti wọn ran wọn ni wọn n jẹ.
Amọ sibẹ naa, ariwo OGD lawọn alatilẹyin ọkunrin naa pa ṣugbọn tawọn to wa ni gbọngan naa ko ri ro.
Ninu ọrọ Sẹnetọ Gbenga Daniel, o jẹ ki araye mọ iwa tawọn ti wọn jọ wa ninu ẹgbẹ naa hu, eyi to ni o tabuku oun.
O sọ pe, "Ọrọ ipinlẹ yii ti a n ba bọ gbogbo nnkan to ba gbɛ lawọn yoo fi fun, ipade ẹgbẹ oṣelu Ogun East, ni a wa ṣe, mo si ti debẹ ki aago mẹwaa ti wọn pe to pe.
"Ibẹ ni mo wa ti wọn ko jẹ ki n wọle yii, nitori naa ti wọn ba ṣe nnkan ti mi o si nibẹ, ofo ni, nitori pe laiku ẹgiri, a ko le fi aawọ ẹ ṣe gbẹdu.
Ṣugbọn ko sẹni to ri ohun to waye naa ti wọn ko sọ pe o lọwọ awọn kan ninu ti wọn wa nijọba ati pe ere ọmọde ni.
No comments:
Post a Comment