Mo ṣetan lati gbajọba lọwọ APC nipinlẹ Ogun lọdun 2027-Oludije gomina APM - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 9 April 2026

Mo ṣetan lati gbajọba lọwọ APC nipinlẹ Ogun lọdun 2027-Oludije gomina APM

Oludije Gomina fẹgbẹ oṣelu Allied People Movement APM, nipinlẹ Ogun, Babajide Rotimi ti sọ pẹlu igboya pe oun ti ṣetan lati le ẹgbẹ oṣelu APC kuro ninu ibo to n bọ lọdun 2027, nitori asiko Ọlọrun fun oun ni eleyii.

O sọrọ yii lakooko to lọọ farahan awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni ọfiisi wọn to wa ni Ijẹja niluu Abẹokuta.

Oludije naa sọ pe ki i ṣe oun deedee jade  bi ko ṣe pe o lọwọ Ọlọrun to ṣẹda oun ninu pe akoko to lati jade.
Babajide tun ṣalaye siwaju pe akoko ti to lati gba akoso ati pe oun ṣetan pẹlu igboya lati koju pamari lakooko to ba yẹ.

Babajide to jẹ ọjọgbọn nidii iṣẹ awọnlẹ tun fikun ọrọ ẹ pe erongba oun fun ipinlẹ Ogun ni lati tunbọ mu idagbasoke ba imayedẹrun fawọn araalu.

O tun tẹsiwaju ninu ọrọ ẹ pe "Ipinlẹ Ogun fẹẹ ilọsiwaju, ṣugbọn o waa da lori bi o ba ṣe nawo, bi o ba ṣe le ṣiṣe lee lori ati bi o ba ṣe le mu nnkan rere ba araalu.

Lori awọn nnkan to ni lọkan lati ṣe, o sọ pe gbogbo ẹ ni yoo da lori bi ogo ipinlẹ Ogun yoo ṣe tunbọ goke si.

O waa sọ pe bi oun ṣe yọju lọjọ naa ni lati waa ki wọn, ki oun si mọ wọn, akoko si n bọ foun lati wa kede gẹgẹ bi oludije.

Nigba to n kii kaabọ lọjọ naa alaga ẹgbẹ ọhun Sanyaolu Abayọmi, to tun jẹ alaga fẹgbẹ apapọ ẹgbẹ oṣelu nipinlẹ Ogun, sọ pe tayọtayọ lawọn fi ki oludije naa.

O sọ di mimọ pe awọn nigbagbọ ninu Ọlọrun ati pe tọkantọkan lawọn fi gba a wọle ṣugbọn ko mọ daju pe awọn oludije mi in naa ṣi n bọ o.

Abayọmi tun sọ pe gbogbo awọn iriri ati irinajo ẹ ninu oṣelu ti fi han pe o to gbangba sun lọyẹ ati pe ko sile ya.

No comments:

Post a Comment

Pages