Lanre Adeyẹmi jade lati dupo ọmọ ile igbimọ aṣofin ni ẹgbẹ PDP l'agbegbe Ọdẹda - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday, 21 April 2026

Lanre Adeyẹmi jade lati dupo ọmọ ile igbimọ aṣofin ni ẹgbẹ PDP l'agbegbe Ọdẹda

Ọnarebu Lanre Adeyẹmi tọpọ mọ si Tẹtu, ti sọ pe ko si nnkan to tun le mu oun pada sẹyin nitori oun ti gbaradi lati dije fun ọmọ ile igbimọ aṣofin ni agbegbe Ọdẹda, labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, ninu ibo ọdun 2027.

O sọrọ yii lakooko to n farahan gẹgẹ bi oludije, eyi to waye ni ọfiisi ẹgbẹ naa to wa ni Ọdẹda, nipinlẹ Ogun.

O kọkọ dupẹ lọwọ awọn agba atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọdẹda, fun bi wọn ṣe faaye gba oun lati fi erongba han gẹgẹ bi oludije.

O ṣalaye pe lori bi wọn ṣe panupọ mu oludije iyẹn 'Concensus', o ni gẹgẹ bi wọn ṣe maa n wi pe ẹgbẹ lagbara ju ati pe awọn ko le kọ ọrọ si agbaagba lẹnu.

Adeyẹmi sọ pe, "Nnkankan to da mi loju ni pe bi a ba to bo ṣe yẹ ka too, ki a ṣe nnkan to ba yẹ, mo ri ara mi gẹgẹ bi ẹni to kun oju oṣuwọn lati ṣe aṣoju PDP ni Ọdẹda nibi"

O ni adura oun ni pe ki Ọlọrun lo ẹgbẹ foun, ki wọn fun ni tikẹẹti pẹlu ileri pe oun ko nii doju ti wọn.

Lori ọrọ pe o lee fi ẹgbẹ silẹ,oludije ọhun sọ pe ibi tawọn de lonii, odo kii ṣan ko boju wo ẹyin.Kii ṣe pe awọn yoo fi ẹgbẹ silẹ lọọ darapọ mọ omiin, amọ igbagbọ oun duro pe oun ni wọn yoo fa kalẹ.

Bẹẹ lo ṣalaye pe oun ko ri awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ti wọn fi asia PDP wọle, amọ ti wọn darapọ mọ APC, nitori nigba mii in ootọ ọrọ a maa sọnu, oun ni lero pe ẹgbẹ ko nii ṣe aṣiṣe bẹẹ mọ, nitori oun lo foju han sita.

O ni,"Ọpọ ninu awọn ti wọn ṣe bẹẹ aṣawọ ni wọn, aṣawọ  ni pe ko ti pẹ ninu ẹgbẹ, to ti farajin,o o le jiya ẹgbẹ ko wọle, ko firu ẹgbẹ bẹẹ silẹ, ṣugbọn to ba jẹ pe o lo oṣu meji lọ, ti wọn fun ẹ ni tikẹẹti, o ṣee ṣe ko wa tan wa.'

O lo akoko naa lati rọ awọn olori ẹgbẹ PDP, ki wọn roo daadaa lọtẹ yii o.

Ninu ọrọ Ọnarebu Kayọde Akintunde tọpọ mọ si Azinge, toun naa ti jẹ alaga ri nijọba ibilẹ Ọdẹda, o sọ pe o ti to bi awọn mẹrin ti wọn ti jade dupo yii amọ ki wọn gba pe oṣelu yii ki i ṣe, bo o pa,o buu lẹsẹ,awọn yoo panupọ mu ẹnikan laarin wọn ni.

O sọ pe fun igba pipẹ sẹyin, igba akọkọ ree ti ẹgbẹ wọn yoo wa ni isọkan ti ko ọrọ kọọtu kankan nilẹ, ki wọn ma baa tun da wahala silẹ lawọn ṣe gbe igbesẹ ọhun.

O waa mu awọn ọmọ ipinlẹ Ogun loju pe didun ni ọsan PDP yoo so, ti ko si ni walẹ mọ

No comments:

Post a Comment

Pages