Latigba ti fọto kan nibi ti Aarẹ orileede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu pẹlu Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ oludije fun ipo gomina nipinlẹ Ogun ti jọ duro ti ara wọn lẹyin ti wọn pari ipade ti wọn ṣe, ni a gbọ pe idaamu ti de bawọn oludije gomina kan, ti ọkan wọn ko si balẹ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni wọn ko nii lọkan pe Senetọ Iyabọ Ọbasanjọ le ni iru igbesẹ bẹẹ lọkan lati ṣe ipade pọ pẹlu aarẹ, nibi to ti lọọ fi erongba ẹ han pe oun fẹẹ jade dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun.
Ati pe loju ọpọ awọn ti wọn jọ dupo, ero wọn ni pe ko sibi ti obinrin naa lọ ṣugbọn to ti jẹ ko ye wọn, idije ipo gomina yii ki i sọrọ ere rara ni, oun fẹẹ gba tikẹẹti lati dije pẹlu igbagbọ pe oun yoo wọle.
Ohun ti wọn lo wa n ko girigiri bawọn oludije gomina kan ti wọn ro pe awọn nikan lawọn ni oore ọfẹ lati ri aarẹ nitori awọn sunmọ ọn daadaa ni bi Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ ṣe rapala de ọdọ aarẹ.
Ohun tawọn kan sọ ni latigba ti wọn ti ri Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, aarẹ tẹlẹ lorileede yii ati ọmọ ẹ Iyabọ Ọbasanjọ nibi ayẹyẹ ṣiṣi papakọ ofurufu to waye lopin ọsẹ to kọja ni Ipẹru.
Ṣugbọn ṣa, ohun ta a gbọ pe o mu Iyabọ Ọbasanjọ lọọ ki Aarẹ Tinubu ni lati fi erongba ẹ han fun ipo gomina atawọn eto to ni fun ipinlẹ Ogun lati le jẹ ki idagbasoke ati ilọsiwaju tubọ deba ipinlẹ Ogun.
Bẹẹ lo ṣeleri lati fi atilẹyin ẹ han si Aarẹ Tinubu fun ipadabọ ẹ ni ẹlẹẹkeji ati pe tọkantọkan loun fi duro ti ẹgbẹ oṣelu APC.
No comments:
Post a Comment