Ninu atẹjade ti ọkunrin naa fi sita lo tako awọn ahesọ kan ti wọn ni wọn gbe kaakari pe ẹgbẹ naa ti mu awọn oludije ti wọn fẹẹ lo fun ipo sẹnetọ ninu ibo ọdun 2027.
Alukoro naa sọ pe ko si nnkan to jọ ọ ninu ipade tawọn ṣe nirọlẹ ọjọ Aje, Monde, to kọja, ibi ti wọn ti ri iroyin ẹlẹjẹ naa ni ko ye oun.
O ṣalaye pe nibi ipade tawọn ṣe lọjọ naa lawọn ti fẹnu ko lori Sẹnetọ Ọlamilekan Adeọla Yayi, gẹgẹ bi oludije fun ipo gomina, bẹẹ lawọn si fọwọ si ipadabọ Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, lẹẹkeji, nnkan meji tawọn jiroro le lori niyẹn.
O waa rọ awọn araalu lati ma ṣe tẹti si awọn ahesọ ti wọn fẹẹ fi maa ba nnkan jẹ nigboro.
No comments:
Post a Comment