Atẹjade kan to tẹ wa lọwọ fi ye wa pe lati ọjọ Ajè, Monde, ọjọ kẹtala, oṣu yii baalu naa yoo bẹrẹ si ni gbe awọn arinrinajo de awọn bii Abuja, Jos, Port Harcourt, Calabar ati Kano.
A tun gbọ pe lati ọjọ Aje Mọnde si ọjọ Ẹti, Furaide ni yoo maa ṣiṣẹ ati pe ẹgbẹrun lọna ọgọrun un naira ni owo ẹ ti bẹrẹ.
Wọn ni eyi jẹ ona ti yoo mu irọrun bawọn arinrinajo ati ọna lati pawo wọle ti yoo si mu ọrọ aje tun dagbasoke kaakiri orileede yii.
Wọn ti waa rọ awọn arinrinajo lati tete waa maa gba aye silẹ fun ibikibi ti wọn ba lọ pẹlu idaniloju pe aabo to peye yoo maa wa fun lilọ ati bibọ.
No comments:
Post a Comment