Awọn ọmọlẹyin Gbenga Daniel ti sọrọ: A ko le gba kawọn ọmọ ẹyin Dapọ Abiọdun ba ẹgbẹ APC jẹ ni Ogun East. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 23 April 2026

Awọn ọmọlẹyin Gbenga Daniel ti sọrọ: A ko le gba kawọn ọmọ ẹyin Dapọ Abiọdun ba ẹgbẹ APC jẹ ni Ogun East.

Johnson Akinpelu 

Awọn ọmọ ẹyin Sẹnetọ Gbenga Daniel, to n ṣoju ẹkun Ogun East nile igbimọ aṣofin agba ti wọn da BAT/OGD,silẹ ti sọ pe gbogbo iwa tawọn ọmọ ẹyin Gomina Dapọ Abiọdun lati ọjọ Aje Monde oṣẹ yii bigba ti wọn fẹẹ fi da wahala silẹ ni agbegbe naa ni tawọn ko si nii gba fun wọn.

Ọrọ yii jade nibi ipade oniroyin to waye lonii niluu Ṣagamu, ipinlẹ Ogun, bẹẹ ni wọn sọ pe titi di akoko yii lawọn ṣi n ṣe atilẹyin fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu  fun ipadabọ  ẹlẹẹkeji  ẹ.

Ninu ọrọ Ọtunba Tayọ Ọnayẹmi, to jẹ alakoso agba fun BATOGD, o sọ pe ko sibi ti wọn ti le ṣe itẹwọgba ọna tawọn ọmọ ẹyin Dapọ Abiọdun ṣe mu ọga wọn gẹgẹ bi oludije fun ipo Sẹnetọ fun ẹkun Ogun East.

O ni ọrọ wọn ko yatọ si awọn to n ṣere ori itage, nitori wọn ti pin ipa ti onikaluku maa ko lọjọ naa.

Ọkunrin naa tun ṣalaye siwaju pe awọn ti Gomina yan ni oore ọfẹ lati yan ẹni to ba wu wọn, amọ bi wọn ṣe lo orukọ ẹgbẹ lati fi ṣe magomago jẹ nnkan to buru jai.

O ṣalaye pe iru ipade alẹnulọrọ awọn agba ẹgbẹ to waye ọhun, o yẹ ki Sẹnetọ Gbenga Daniel atawọn agba mii in wa nibe  amọ Iyalẹnu lo jẹ pe awọn ti wọn kora wọn jọ lọjọ naa ni wọn ko to oṣuwọn lati wa nibẹ.

Ọtunba Ọnayẹmi tun fikun un pe ọpọ awọn to yẹ ko wa nibẹ ti wọn ko jẹ ni wọn sọ ọ loju wọn pe ipade D A ni eleyii ki wọn ba ẹsẹ wọn sọrọ ti wọn ko ba fẹẹ ki wọn ṣe kinni yẹn fun wọn.

Alakoso gbogboogbo BATOGD tun sọ pe" Awa ko le sọ fun wọn pe ki wọn ma ṣe nnkan ti ọga wọn ran wọn, a si mọ pe nitori ẹ ni wọn ko ṣe jẹ ki Ọtunba Gbenga Danie wọle sibi ipade ọhun, ṣugbọn wọn ko ba ti ni igboya lati sọ nita gbangba nnkan ti wọn ni lero"

Bẹẹ ni ọkunrin naa tun mẹnuba iwa aibikita to tun ni wọn hu lori bi wọn ṣe ko ọlọpaa lọọ sile Ọtunba Gbenga Daniel to wa ni Ọbanta, lọjọ kejilelogun, oṣu yii nitori ki wọn ma ba a ṣe eto BATOGD, ti wọn ti maa n ṣe lawọn ijọba ibilẹ to we labẹ Ogun East.

O fẹsun kan pe boya  o ni awọn nnkan ti ko ri bẹẹ ti alaga kansu Ijẹbu Ode lọọ sọ fawọn alaabo ilu lo jẹ ki wọn gbe iru igbesẹ bẹẹ.

BATOGD tun waa lo akoko naa lati fi atilẹyin wọn han si Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu fun ipadabọ sipo aarẹ ni ẹlẹẹkeji .

Wọn wa sọ di mimọ iwọde BATOGD nibi ti wọn ti maa n ṣe agbeyẹwo iṣẹ aṣofin wọn nile igbimọ aṣofin agba ti wọn ti bẹrẹ lọdun to kọja yoo tẹsiwaju laipẹ pẹlu ironilagbara ti wọn maa n ṣe.

No comments:

Post a Comment

Pages