Ninu atẹjade ti wọn fi sita ni Lẹmọ ti ṣapejuwe Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ gẹgẹ bi aṣaaju rere, ti ko ṣe fi lafiwe, pẹlu awọn awokọṣe rere to ṣe e tọka si.
Oludije Gomina naa tun sọ pe " Baba, mo darapọ mọ awọn ọmọ orileede Naijiria paapaa julọ awa ta a jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ogun, lati ki yin ku oriire ọjọọbi ọdun mọkandinlaadọrun, ti ẹ pẹ lorilẹ alaye.
" Awọn ẹri rere lo ti wa nilẹ fawọn ohun ribiribi tẹ ẹ ti fi igbe aye yin ṣe fun ifarajin lati le je ki alaafia jọba lorileede Naijiria.
"Bakan naa ipa yin ko kere ninu ijọba tiwa-n-tiwa, dẹmokireesi, ifọwọsowọpọ lati ma jẹ ki ẹlẹyamẹya waye, aṣaaju rere, to ti fipa rere ti ko ṣe gbagbe lelẹ.Bẹẹ lawọn ipa yin ko tun kere nilẹ Afrika ati gbogbo agbaye"
O waa gbadura pe ki Ọlọrun tunbọ lọra ẹmi Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ pẹlu ẹmi gungun, ibukun ati alaafia nla.
No comments:
Post a Comment